JẸNẸSISI 9:18-29

JẸNẸSISI 9:18-29 YCE

Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani. Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé. Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà. Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò. Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde. Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn. Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i, Ó ní, “Ẹni ègún ni Kenaani, ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.” Ó tún fi kún un pé, “Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu, ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe. Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ, kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu, ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.” Ọọdunrun ọdún ó lé aadọta (350) ni Noa tún gbé sí i lẹ́yìn ìkún omi. Noa kú nígbà tí ó di ẹni ẹgbẹrun ọdún ó dín aadọta (950).