Gẹn 9:18-29
Gẹn 9:18-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọ Noa, ti o si jade ninu ọkọ̀ ni Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti: Hamu si ni baba Kenaani. Awọn mẹta wọnyi li ọmọ Noa: lati ọdọ wọn li a gbé ti tàn ká gbogbo aiye. Noa si bẹ̀rẹ si iṣe àgbẹ, o si gbìn ọgbà-àjara: O si mu ninu ọti-waini na, o mu amupara; o si tú ara rẹ̀ si ìhoho ninu agọ́ rẹ̀. Hamu, baba Kenaani, si ri ìhoho baba rẹ̀, o si sọ fun awọn arakunrin rẹ̀ meji lode. Ati Ṣemu ati Jafeti mu gọgọwu, nwọn si fi le ejika awọn mejeji, nwọn si fi ẹhin rìn, nwọn si bò ìhoho baba wọn; oju wọn si wà lẹhin; nwọn kò si ri ìhoho baba wọn. Noa si jí kuro li oju ọti-waini rẹ̀, o si mọ̀ ohun ti ọmọ rẹ̀ kekere ṣe si i. O si wipe, Egbe ni fun Kenaani; iranṣẹ awọn iranṣẹ ni yio ma ṣe fun awọn arakunrin rẹ̀. O si wipe, Olubukun li OLUWA Ọlọrun Ṣemu; Kenaani yio ma ṣe iranṣẹ rẹ̀. Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ́ Ṣemu; Kenaani yio si ma ṣe iranṣẹ wọn. Noa si wà ni irinwo ọdun o din ãdọta, lẹhin ìkún-omi. Gbogbo ọjọ́ Noa jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí ãdọta: o si kú.
Gẹn 9:18-29 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani. Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé. Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà. Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò. Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde. Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn. Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i, Ó ní, “Ẹni ègún ni Kenaani, ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.” Ó tún fi kún un pé, “Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu, ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe. Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ, kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu, ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.” Ọọdunrun ọdún ó lé aadọta (350) ni Noa tún gbé sí i lẹ́yìn ìkún omi. Noa kú nígbà tí ó di ẹni ẹgbẹrun ọdún ó dín aadọta (950).
Gẹn 9:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani). Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Noa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé. Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn. Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. Ó wí pé: “Ègún ni fún Kenaani. Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.” Ó sì tún wí pé; “Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run Ṣemu Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu. Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀, Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.” Noa wà láààyè fún irínwó ọdún ó-dínàádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.