JẸNẸSISI 21:1-6

JẸNẸSISI 21:1-6 YCE

OLUWA bẹ Sara wò gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ó sì ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Sara lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún Abrahamu lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ní àkókò tí Ọlọrun sọ fún un. Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki. Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. Abrahamu jẹ́ ẹni ọgọrun-un (100) ọdún nígbà tí a bí Isaaki fún un. Sara wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ni yóo sì rẹ́rìn-ín.”