Gẹn 21:1-6
Gẹn 21:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì bẹ Sara wò bí ó ti wí, OLúWA sì ṣe fún Sara gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. Sara sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Abrahamu ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un. Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki. Nígbà tí Isaaki pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Abrahamu sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki. Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”
Gẹn 21:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si bẹ̀ Sara wò bi o ti wi, OLUWA si ṣe fun Sara bi o ti sọ. Sara si loyun, o si bí ọmọkunrin kan fun Abrahamu li ogbologbo rẹ̀, li akokò igbati Ọlọrun dá fun u. Abrahamu si pè orukọ ọmọ rẹ̀ ti a bí fun u, ni Isaaki, ẹniti Sara bí fun u. Abrahamu si kọ Isaaki ọmọ rẹ̀ ni ilà, nigbati o di ọmọ ijọ́ mẹjọ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdún, nigbati a bí Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u. Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi.
Gẹn 21:1-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bẹ Sara wò gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ó sì ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Sara lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún Abrahamu lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ní àkókò tí Ọlọrun sọ fún un. Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki. Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. Abrahamu jẹ́ ẹni ọgọrun-un (100) ọdún nígbà tí a bí Isaaki fún un. Sara wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ni yóo sì rẹ́rìn-ín.”