Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni.
Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji.
Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta.