Gẹn 1:1-13

Gẹn 1:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni. Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta.

Gẹn 1:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “ọ̀sán,” àti òkùnkùn ní “òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “ọ̀run.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹta.