ISIKIẸLI 28:11-14

ISIKIẸLI 28:11-14 YCE

OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan. O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ. Mo fi kerubu tí a fi àmì òróró yàn tì ọ́. O wà lórí òkè mímọ́ èmi Ọlọrun, o sì ń rìn láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.