Esek 28:11-14
Esek 28:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, pohùnréré sori ọba Tire, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi dí iye na, o kún fun ọgbọ́n, o si pé li ẹwà. Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ. Iwọ ni kerubu ti a nà ti o si bò; emi si ti gbe ọ kalẹ: iwọ wà lori oke mimọ́ Ọlọrun; iwọ ti rìn soke rìn sodò lãrin okuta iná.
Esek 28:11-14 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan. O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ. Mo fi kerubu tí a fi àmì òróró yàn tì ọ́. O wà lórí òkè mímọ́ èmi Ọlọrun, o sì ń rìn láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.

Esek 28:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA tún tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: “ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà, o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà. Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run; onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ; sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì, àti jasperi, safire, emeradi, turikuoṣe, àti karbunkili, àti wúrà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà, láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn. A fi ààmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù, torí èyí ni mo fi yàn ọ́. Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run; ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná