ISIKIẸLI 15

15
Òwe Nípa Igi Àjàrà
1OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2“Ìwọ ọmọ eniyan, ọ̀nà wo ni ẹ̀ka igi àjàrà gbà dára ju ẹ̀ka igi yòókù lọ; àní igi àjàrà tí ó wà láàrin àwọn igi inú igbó? 3Ǹjẹ́ ẹnìkan a máa fi igi rẹ̀ ṣe ohunkohun? Àbí wọn a máa gé lára rẹ̀ kí wọn fi gbẹ́ èèkàn tí wọ́n fi ń so nǹkan mọ́lẹ̀? 4Iná ni wọ́n ń fi í dá, nígbà tí iná bá jó o lórí, tí ó jó o nídìí, tí ó sì sọ ààrin rẹ̀ di èédú, ṣé ó tún ṣe é fi ṣe ohunkohun? 5Nígbà tí ó wà ní odidi, kò wúlò fún nǹkankan. Nígbà tí iná ti jó o, tí ó ti di èédú, ṣé eniyan tún lè fi ṣe ohunkohun?”
6Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ẹ̀ka àjàrà tí mo sọ di igi ìdáná láàrin àwọn igi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. 7N óo dójú lé wọn, bí wọn tilẹ̀ yọ jáde ninu iná, sibẹsibẹ iná ni yóo jó wọn. Nígbà tí mo bá dójú lé wọn, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. 8N óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro nítorí pé wọ́n ti hùwà aiṣootọ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 15: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀