ISIKIẸLI 16

16
Ìtàn Jerusalẹmu
1OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2“Ìwọ ọmọ eniyan, fi nǹkan ìríra tí Jerusalẹmu ń ṣe hàn án, 3kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé:
“Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ. 4Bí wọn ṣe bí ọ nìyí: nígbà tí wọ́n bí ọ, wọn kò dá ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi omi wẹ̀ ọ́. Wọn kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn kò sì fi aṣọ wé ọ. 5Ẹnikẹ́ni kò wò ọ́ lójú, kí ó ṣàánú rẹ, kí ó ṣe ọ̀kan kan ninu àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì fún ọ. Ṣugbọn wọ́n gbé ọ sọ sinu pápá, nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ.
6“Bí mo tí ń rékọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo rí ọ tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀. Bí o tí ń yí ninu ẹ̀jẹ̀, mo bá sọ fún ọ pé kí o yè, 7kí o sì dàgbà bí irúgbìn oko. Ni o bá dàgbà, o ga, o sì di wundia, ọyàn rẹ yọ, irun rẹ sì hù, sibẹ o wà ní ìhòòhò.
8“Ìgbà tí mo tún kọjá lọ́dọ̀ rẹ, tí mo tún wò ọ́, o ti dàgbà o tó gbé. Mo bá da aṣọ mi bò ọ́, mo fi bo ìhòòhò rẹ. Mo ṣe ìlérí fún ọ, mo bá ọ dá majẹmu, o sì di tèmi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9“Lẹ́yìn náà, mo mú omi, mo wẹ̀ ọ́; mo fọ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára. 10Mo wá wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí wọ́n ṣe ọnà sí lára, mo wọ̀ ọ́ ní bàtà aláwọ. Mo wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, mo sì dá ẹ̀wù siliki fún ọ. 11Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́; mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn. 12Mo fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tí ó lẹ́wà dé ọ lórí. 13Bẹ́ẹ̀ ni mo fi wúrà ati fadaka ṣe ọ̀ṣọ́ sí ọ lára. Aṣọ funfun ati siliki tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni mo dá fún ọ. Ò ń jẹ burẹdi tí ó dùn, tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tí ó kúnná ṣe, ò ń lá oyin ati òróró; o dàgbà, o sì di arẹwà, o dàbí Ọbabinrin. 14Òkìkí ẹwà rẹ wá kàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè; o dára nítorí pé èmi ni mo fún ọ ní ẹwà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
15“Ṣugbọn o gbójú lé ẹwà rẹ; o di alágbèrè ẹ̀sìn nítorí òkìkí rẹ, o sì ń bá gbogbo àwọn eniyan tí wọn ń kọjá ṣe àgbèrè. 16O mú ninu àwọn aṣọ rẹ, o fi ṣe ojúbọ aláràbarà, o sì ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́. 17O mú ninu àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka rẹ, tí mo fún ọ, o fi wọ́n ṣe ère ọkunrin, o sì ń bá wọn ṣe àgbèrè. 18O mú aṣọ rẹ tí a ṣe ọnà sí lára, o dà á bò wọ́n. O gbé òróró ati turari mi kalẹ̀ níwájú wọn. 19Bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ tí mo fún ọ. Mo fún ọ ní ìyẹ̀fun tí ó kúnná, ati òróró, ati oyin pé kí o máa jẹ, ṣugbọn o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
20“O mú àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati àwọn ọmọ rẹ obinrin tí o bí fún mi, o fi wọ́n rú ẹbọ ohun jíjẹ fún àwọn oriṣa. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ni o pe ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè ẹ̀sìn rẹ, 21tí o fi ọ̀bẹ dú àwọn ọmọ mi, o fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí àwọn oriṣa? 22Nígbà tí ò ń ṣe àgbèrè ati gbogbo nǹkan ìríra rẹ, o kò ranti ìgbà èwe rẹ, nígbà tí o wà ní ìhòòhò goloto, tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀!”
Ìgbé-Ayé Jerusalẹmu Gẹ́gẹ́ Bí Alágbèrè Ẹ̀sìn
23OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ ibi wọnyi, o gbé! O gbé! 24O mọ ilé gíga fún ara rẹ ní gbogbo gbàgede, o tẹ́ ìtẹ́ gíga fún ara rẹ ní ìta gbangba. 25O mọ ìtẹ́ gíga ní òpin gbogbo òpópó. O sì ń ba ẹwà rẹ jẹ́ níbẹ̀, ò ń ta ara rẹ fún gbogbo ọkunrin tí wọn ń kọjá, o sì sọ àgbèrè rẹ di pupọ. 26O tún ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu àwọn ará Ijipti, àwọn aládùúgbò rẹ, oníṣekúṣe. Ò ń mú kí ìwà àgbèrè rẹ pọ̀ sí i láti mú mi bínú.
27“Ọwọ́ mi wá tẹ̀ ọ́, mo mú ọ kúrò ninu ẹ̀tọ́ rẹ. Mo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ fi ìwọ̀ra gba ohun ìní rẹ, àwọn ará Filistini tí ìwà burúkú rẹ ń tì lójú.
28“O bá àwọn ará Asiria ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu, nítorí pé o kò ní ìtẹ́lọ́rùn sibẹ, lẹ́yìn gbogbo àgbèrè tí o ṣe pẹlu wọn, o kò ní ìtẹ́lọ́rùn. 29O tún ṣe àgbèrè lọpọlọpọ pẹlu àwọn oníṣòwò ará ilẹ̀ Kalidea, sibẹsibẹ, kò tẹ́ ọ lọ́rùn.”
30OLUWA Ọlọrun ní ọkàn rẹ ti kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jù! Ó ń wò ọ́ bí o tí ń ṣe gbogbo nǹkan wọnyi bí alágbèrè tí kò nítìjú! 31O mọ ilé oriṣa sí òpin gbogbo òpópó, o sì ń kọ́ ibi ìrúbọ sí gbogbo gbàgede. Sibẹ o kò ṣe bí àwọn alágbèrè, nítorí pé o kò gba owó. 32Ìwọ iyawo onípanṣágà tí ò ń kó àwọn ọkunrin ọlọkunrin wọlé dípò ọkọ rẹ. 33Ọkunrin níí máa ń fún àwọn aṣẹ́wó ní ẹ̀bùn, ṣugbọn ní tìrẹ, ìwọ ni ò ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn. O fi ń tù wọ́n lójú, kí wọ́n lè máa wá bá ọ ṣe àgbèrè láti ibi gbogbo. 34Àgbèrè tìrẹ yàtọ̀ sí ti àwọn aṣẹ́wó yòókù, kò sí ẹni tí ń wá ọ láti bá ọ ṣe àgbèrè; ìwọ ni ò ń fún ọkunrin ní ẹ̀bùn dípò kí wọ́n fún ọ! Èyí ni àgbèrè tìrẹ fi yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlòmíràn.
Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Jerusalẹmu
35Nítorí náà, ìwọ aṣẹ́wó yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí.
36OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwà ìtìjú rẹ ti hàn sí gbangba, o bọ́ra sí ìhòòhò níta, nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣe àgbèrè, tí ò ń bọ àwọn oriṣa rẹ, o sì pa àwọn ọmọ rẹ, o fi wọ́n rúbọ sí àwọn oriṣa. 37Wò ó! N óo kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ, tí inú rẹ dùn sí jọ, ati àwọn tí o fẹ́ràn ati àwọn tí o kórìíra, ni n óo kó wá láti dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà. N óo tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, kí wọ́n lè rí ìhòòhò rẹ. 38N óo ṣe ìdájọ́ fún ọ bí wọn tí ń ṣe ìdájọ́ fún àwọn obinrin tí wọ́n kọ ọkọ sílẹ̀, tabi àwọn tí wọ́n paniyan. N óo fi ìtara ati ibinu gbẹ̀san ìpànìyàn lára rẹ. 39N óo fi ọ́ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn óo wó ilé oriṣa ati ibi ìrúbọ rẹ palẹ̀. Wọn óo tú aṣọ rẹ, wọn óo gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò.
40“Wọn óo kó àwọn ọmọ ogun wá bá ọ, wọn óo sọ ọ́ lókùúta, wọn óo sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́. 41Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́. 42Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára rẹ, n kò sì ní jowú nítorí rẹ mọ́. Ara mi yóo rọlẹ̀, inú kò sì ní bí mi mọ́. 43Nítorí pé o kò ranti ìgbà èwe rẹ, ṣugbọn o mú mi bínú nítorí nǹkan wọnyi. Nítorí náà n óo da èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lé ọ lórí. Ṣé o kò tún ti fi ìwà ainitiju kún ìwà ìríra rẹ?” OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
Bí Ìyá Ti Rí Ni Ọmọ Rẹ̀ Obinrin Náà Rí
44OLUWA ní: “Gbogbo eniyan ni yóo máa pa òwe yìí mọ́ ìwọ Jerusalẹmu pé: ‘Òwú ìyá gbọ̀n ni ọmọ óo ran, bí ìyá bá ti rí ni ọmọ rẹ̀ obinrin yóo rí.’ 45Ọmọ bíbí inú ìyá rẹ ni ọ́, tí kò bìkítà fún ọkọ ati àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwà kan náà ni ó wà lọ́wọ́ ìwọ ati àwọn arabinrin rẹ, àwọn náà kò ka ọkọ ati àwọn ọmọ wọn sí. Ará Hiti ni ìyá rẹ, ará Amori sì ni baba rẹ.
46“Samaria ni ẹ̀gbọ́n rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà àríwá. Sodomu ni àbúrò rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà gúsù. 47Títẹ̀lé ìṣe wọn nìkan kò tẹ́ ọ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni ṣíṣe ohun ìríra bíi tiwọn kò tó ọ. Láìpẹ́ ọjọ́, ìwà tìrẹ gan-an yóo burú ju tiwọn lọ.
48“Èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, Sodomu arabinrin rẹ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò tíì ṣe tó ohun tí ìwọ ati àwọn ọmọbinrin rẹ ṣe. 49Ohun tí Sodomu arabinrin rẹ ṣe tí kò dára ni pé: Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ní ìgbéraga. Wọ́n ní oúnjẹ lọpọlọpọ, ara sì rọ̀ wọ́n, ṣugbọn wọn kò ran talaka ati aláìní lọ́wọ́. 50Wọ́n gbéraga, wọ́n sì ṣe nǹkan ìríra níwájú mi. Nítorí náà, nígbà tí mo rí ohun tí wọn ń ṣe, mo pa wọ́n run.
51“Ẹ̀ṣẹ̀ tí Samaria dá kò tó ìdajì èyí tí ìwọ dá, ohun ìríra tí o ṣe sì jù tiwọn lọ. O ti mú kí arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí pé nǹkan ìríra tí o ṣe pọ̀ pupọ ju tirẹ̀ lọ. 52Ó yẹ kí ojú ti ìwọ pàápàá, nítorí o ti jẹ́ kí ìdájọ́ gbe àwọn arabinrin rẹ, nítorí nǹkan ìríra tí o ṣe ju tiwọn lọ. Ọ̀nà wọn tọ́ ju tìrẹ lọ, nítorí náà, ó yẹ kí ojú tì ọ́, nítorí o ti mú kí àwọn arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.”
Ìtura Yóo Pada sí Sodomu ati Samaria
53OLUWA sọ níti Jerusalẹmu pé, “N óo dá ire wọn pada: ire Sodomu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ati ire Samaria ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin. N óo dá ire tìrẹ náà pada pẹlu tiwọn. 54Kí ojú lè tì ọ́ fún gbogbo ohun tí o ṣe tí o fi dá wọn lọ́kàn le. 55Ní ti àwọn arabinrin rẹ: Sodomu ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, Samaria ati àwọn ọmọ rẹ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin náà yóo pada sí ibùgbé yín. 56Ṣebí yẹ̀yẹ́ ni ò ń fi Sodomu arabinrin rẹ ṣe ní àkókò tí ò ń gbéraga, 57kí ó tó di pé àṣírí ìwà burúkú rẹ wá tú? Nisinsinyii ìwọ náà ti dàbí rẹ̀; o ti di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Edomu ati àwọn tí ó wà ní agbègbè wọn, ati lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Filistini, ati àwọn tí wọ́n yí ọ ká, tí wọn ń kẹ́gàn rẹ. 58O óo jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ati àwọn nǹkan ìríra tí o ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Majẹmu Ayérayé
59Láìṣe àní, àní, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣe sí ọ, bí ìwà rẹ. O kò ka ìbúra mi sí, o sì ti yẹ majẹmu mi. 60Sibẹsibẹ, n óo ranti majẹmu tí mo bá ọ dá ní ìgbà èwe rẹ. N óo sì bá ọ dá majẹmu tí kò ní yẹ̀ títí lae. 61O óo wá ranti gbogbo ìwà rẹ, ojú yóo sì tì ọ́ nígbà tí mo bá mú ẹ̀gbọ́n rẹ obinrin ati àbúrò rẹ obinrin, tí mo sì fà wọ́n lé ọ lọ́wọ́ bí ọmọ; ṣugbọn tí kò ní jẹ́ pé torí majẹmu tí mo bá ọ dá ni. 62N óo fìdí majẹmu tí mo bá ọ dá múlẹ̀. O óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. 63Kí o lè ranti, kí ìdààmú sì bá ọ, kí ìtìjú má jẹ́ kí o lè lanu sọ̀rọ̀ mọ́; nígbà tí mo bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀