ISIKIẸLI 12

12
Wolii Gẹ́gẹ́ Bí Ẹni Tí Ó sá fógun
1OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2“Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.#Ais 6:9-10; Jer 5:21; Mak 8:18
3“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. 4Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. 5Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde. 6Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.”
7Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn.
8Ní òwúrọ̀, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, 9ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kò bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ni ò ń ṣe? 10Wí fún wọn pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá àwọn olórí Jerusalẹmu ati àwọn eniyan Israẹli tí ó kù ninu rẹ̀ wí.’ 11Sọ fún wọn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ fún wọn. Bí o ti ṣe ni wọ́n óo ṣe wọ́n, wọn óo lọ sí ìgbèkùn. 12Ẹni tí ó jẹ́ olórí láàrin wọn yóo gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́, yóo sì jáde kúrò nílùú. Yóo dá odi ìlú lu, yóo gba ibẹ̀ jáde. Yóo fi nǹkan bojú kí ó má ba à rí ilẹ̀. 13N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí. 14Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ.#2A. Ọba 25:7; Jer 52:11
15“Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé. 16N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Àmì Wolii Tí Ń Gbọ̀n
17OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18“Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ. 19Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù. 20Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”
Òwe tí Ó Lókìkí ati Iṣẹ́ tí Àwọn Eniyan kò Fẹ́ Gbọ́
21OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 22“Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’ 23Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ.
24“Nítorí pé ìran irọ́ tabi àfọ̀ṣẹ ẹ̀tàn yóo dópin láàrin àwọn ọmọ Israẹli. 25Ṣugbọn èmi OLUWA yóo sọ ohun tí mo bá fẹ́ sọ, yóo sì ṣẹ. Kò ní falẹ̀ mọ́, ṣugbọn níṣojú ẹ̀yin ìdílé ọlọ̀tẹ̀, ni n óo sọ̀rọ̀, tí n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”
26OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, 27“Ìwọ ọmọ eniyan, gbọ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti ń wí pé, Ìran ọjọ́ iwájú ni ò ń rí, o sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ gbọọrọ. 28Nítorí náà, wí fún wọn pé: mo ní n kò ní fi ọ̀rọ̀ mi falẹ̀ mọ́, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ yóo ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 12: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀