ISIKIẸLI 11

11
(OLUWA Bá Jerusalẹmu Wí)
1Ẹ̀mí gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan wà lẹ́nu ọ̀nà náà, mo rí i pé àwọn meji láàrin wọn jẹ́ ìjòyè: Jaasanaya, ọmọ Aṣuri, ati Pelataya, ọmọ Bẹnaya.
2OLUWA sọ fún mi, pé, “Ìwọ Ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbèrò ibi nìyí; tí wọn ń fún àwọn eniyan ìlú yìí ní ìmọ̀ràn burúkú. 3Wọ́n ń wí pé, ‘àkókò ilé kíkọ́ kò tíì tó. Ìlú yìí dàbí ìkòkò,#11:3 Ìkòkò ní ń dáàbò bo ẹran tí à ń sè lọ́wọ́ iná. àwa sì dàbí ẹran.’ 4Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nípa wọn, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀.”
5Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé mi, ó sọ fún mi, pé, “OLUWA ní, Èrò yín nìyí, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò lọ́kàn, 6Ẹ ti pa ọpọlọpọ eniyan ní ààrin ìlú yìí; ẹ sì ti da òkú wọn kún gbogbo ìgboro ati òpópónà ìlú.
7“Nítorí náà, àwọn òkú yín tí ẹ dà sí ààrin ìlú yìí ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò, ṣugbọn n óo mu yín kúrò láàrin rẹ̀. 8Idà ni ẹ̀ ń bẹ̀rù, idà náà ni n óo sì jẹ́ kí ó pa yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀. 9N óo ko yín kúrò ninu ìlú yìí, n óo sì ko yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́. N óo sì ṣe ìdájọ́ yín. 10Idà yóo pa yín, ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. 11Ìlú yìí kò ní jẹ́ ìkòkò fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní jẹ́ ẹran ninu rẹ̀; ní ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín. 12Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.”
13Bí mo tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni Pelataya, ọmọ Bẹnaya, bá kú. Mo bá dojúbolẹ̀, mo kígbe sókè, mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o fẹ́ pa àwọn ọmọ Israẹli yòókù tán ni?”
Ìlérí Ọlọrun sí Àwọn tí Wọ́n Wà Ní Ìgbèkùn
14OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 15“Ìwọ ọmọ eniyan, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn arakunrin wọn, tí ẹ jọ wà ní ìgbèkùn, àní gbogbo ilé Israẹli; wọ́n ń sọ pé, ‘Wọ́n ti lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, OLUWA sì ti fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’
16“Nítorí náà wí fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní, bí mo tilẹ̀ kó wọn lọ jìnnà sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ ayé, sibẹsibẹ mo jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ tí wọ́n lọ.
17“Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’ 18Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀. 19Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran; 20kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn. 21Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”#Isi 36:26-28
Ògo OLUWA Kúrò ní Jerusalẹmu
22Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn. 23Ògo OLUWA gbéra kúrò láàrin ìlú náà, ó sì dúró sórí òkè tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. 24Ẹ̀mí bá gbé mi sókè ní ojúran, ó gbé mi wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ìran tí mo rí bá kúrò lójú mi. 25Mo sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA fihàn mí fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn.#Isi 43:2-5

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 11: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀