Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA.
Kà ẸKISODU 35
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ẸKISODU 35:20-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò