ẸKISODU 35

35
Àwọn ìlànà fún Ọjọ́ Ìsinmi
1Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí: 2Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á. #Eks 20:8-11; 23:12; 31:15; 34:21; Lef 23:3; Diut 5:12-14 3Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”
Àwọn Ẹ̀bùn fún Kíkọ́ Àgọ́ Mímọ́
(Eks 25:1-9)
4Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní, 5‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ, 6aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́; 7awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia, 8òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn, 9òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’
Àwọn Ohun Èlò fún Kíkọ́ Àgọ́ Mímọ́ OLUWA
(Eks 39:32-43)
10“Kí gbogbo ọkunrin tí ó bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ ninu yín jáde wá láti ṣe àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ wọnyi: 11àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn. 12Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀. 13Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀. 14Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn. 15Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. 16Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. 17Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. 18Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn; 19àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.”
Àwọn Eniyan Mú Ọrẹ Wá
20Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose. 21Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa. 22Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA. 23Gbogbo àwọn tí wọ́n ní aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò, tabi aṣọ pupa, tabi aṣọ funfun, tabi irun ewúrẹ́, tabi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, tabi awọ ewúrẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn wá. 24Gbogbo àwọn tí wọ́n lè fi fadaka ati idẹ tọrẹ fún OLUWA ni wọ́n mú wọn wá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí wọ́n ní igi akasia, tí ó wúlò náà mú wọn wá pẹlu. 25Gbogbo àwọn obinrin tí wọ́n mọ òwú ran ni wọ́n ran òwú tí wọ́n sì kó o wá: àwọn òwú aláwọ̀ aró, elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati funfun tí wọ́n fi ń hun aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. 26Gbogbo àwọn obinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún, tí wọ́n sì mọ irun ewúrẹ́ ran, ni wọ́n ran án wá. 27Àwọn àgbààgbà mú òkúta onikisi wá ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà, 28ati oríṣìíríṣìí èròjà ati òróró ìtànná, ati ti ìyàsímímọ́, ati fún turari olóòórùn dídùn. 29Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọkunrin ati lobinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún ni wọ́n mú ọrẹ àtinúwá wá fún OLUWA, láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.
Àwọn Oníṣẹ́ Ọnà fún Àgọ́ Mímọ́ OLUWA
(Eks 31:1-11)
30Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “OLUWA fúnra rẹ̀ ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. 31Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sinu rẹ̀, ó sì ti fún un ní ọgbọ́n, òye, ati ìmọ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, 32láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà; 33láti gé oríṣìíríṣìí òkúta iyebíye ati láti tò wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni igi gbígbẹ́ ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà ṣíṣe. 34Ọlọrun sì ti mí ìmísí rẹ̀ sí i ninu láti kọ́ ẹlòmíràn, àtòun ati Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani. 35Ọlọrun ti fún wọn ní ìmọ̀ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí àwọn oníṣọ̀nà máa ń ṣe, ati ti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati ti àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ, ìbáà jẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò tabi aṣọ pupa tabi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tabi oríṣìí aṣọ mìíràn, gbogbo iṣẹ́ ọnà ni wọn yóo máa ṣe; kò sì sí iṣẹ́ ọnà tí wọn kò lè ṣe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸKISODU 35: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀