Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Gbẹ́ wàláà òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, n óo sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ sára wàláà ti àkọ́kọ́ tí ó fọ́ sára wọn. Múra ní àárọ̀ ọ̀la, kí o gun òkè Sinai wá, kí o wá farahàn mí lórí òkè náà. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá ọ wá, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ sí níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn mààlúù, tabi àwọn aguntan kò gbọdọ̀ jẹ káàkiri níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà.” Mose bá gbẹ́ wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gun òkè Sinai lọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un; ó kó àwọn wàláà òkúta mejeeji náà lọ́wọ́.
OLUWA tún sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu ó dúró níbẹ̀ pẹlu rẹ̀, ó sì pe orúkọ mímọ́ ara rẹ̀. OLUWA kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun aláàánú ati olóore, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní àánú ati òtítọ́. Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.”
Mose yára tẹ orí ba, ó dojú bolẹ̀, ó sì sin OLUWA. Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.”