Eks 34:1-9
Eks 34:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju: emi o si kọ ọ̀rọ walã ti iṣaju, ti iwọ ti fọ́, sara walã wọnyi. Si mura li owurọ̀, ki iwọ ki o si gún òke Sinai wá li owurọ̀, ki o si wá duro niwaju mi nibẹ̀ lori òke na. Ẹnikẹni ki yio si bá ọ gòke wá, ki a má si ṣe ri ẹnikẹni pẹlu li òke na gbogbo; bẹ̃ni ki a máṣe jẹ ki agbo-agutan tabi ọwọ́-ẹran ki o jẹ niwaju òke na. On si gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju; Mose si dide ni kutukutu owurọ̀, o si gún òke Sinai, bi OLUWA ti paṣẹ fun u, o si mú walã okuta mejeji li ọwọ́ rẹ̀. OLUWA si sọkalẹ ninu awọsanma, o si bá a duro nibẹ̀, o si pè orukọ OLUWA. OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ; Ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedede, ati irekọja, ati ẹ̀ṣẹ jì, ati nitõtọ ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijiyà; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn omọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin. Mose si yara, o si foribalẹ, o si sìn. On si wipe, Njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi Oluwa, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Oluwa ki o ma bá wa lọ; nitori enia ọlọrùn lile ni; ki o si dari aiṣẹdede wa ati ẹ̀ṣẹ wa jì, ki o si fi wa ṣe iní rẹ.
Eks 34:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Gbẹ́ wàláà òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, n óo sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ sára wàláà ti àkọ́kọ́ tí ó fọ́ sára wọn. Múra ní àárọ̀ ọ̀la, kí o gun òkè Sinai wá, kí o wá farahàn mí lórí òkè náà. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá ọ wá, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ sí níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn mààlúù, tabi àwọn aguntan kò gbọdọ̀ jẹ káàkiri níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà.” Mose bá gbẹ́ wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gun òkè Sinai lọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un; ó kó àwọn wàláà òkúta mejeeji náà lọ́wọ́. OLUWA tún sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu ó dúró níbẹ̀ pẹlu rẹ̀, ó sì pe orúkọ mímọ́ ara rẹ̀. OLUWA kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun aláàánú ati olóore, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní àánú ati òtítọ́. Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.” Mose yára tẹ orí ba, ó dojú bolẹ̀, ó sì sin OLUWA. Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.”
Eks 34:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé, “E gé òkúta wàláà méjì jáde bí i ti àkọ́kọ́, èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé tó wà lára tí àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fọ́ sára wọn. Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Sinai. Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.” Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀. Nígbà náà ni OLúWA sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ OLúWA. Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “OLúWA, OLúWA, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.” Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn. Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.”