EFESU 4:26-28

EFESU 4:26-28 YCE

Bí ẹ bá bínú, ẹ má jẹ́ kí ibinu mu yín dẹ́ṣẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ ba yín ninu ibinu. Ẹ má fi ààyè gba Èṣù. Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kúkú gbìyànjú láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kí òun náà lè ní ohun tí yóo fún àwọn aláìní.