EFESU 2:14-16

EFESU 2:14-16 YCE

Nítorí pé Kristi yìí ni alaafia wa. Òun ni ó sọ àwọn tí wọ́n kọlà ati àwọn tí kò kọlà di ọ̀kan. Nígbà tí ó gbé ara eniyan wọ̀, ó wó ògiri ìkélé tí ó wà láàrin wọn tí wọ́n fi ń yan ara wọn lódì. Ó sọ òfin ati àwọn ìlànà ati àṣẹ di nǹkan yẹpẹrẹ, kí ó lè sọ àwọn mejeeji di ẹ̀dá titun kan náà ninu ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú alaafia wá sáàrin wọn. Ó làjà láàrin àwọn mejeeji, ó sọ wọ́n di ara kan lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa agbelebu. Ó ti mú odì yíyàn dópin lórí agbelebu.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú EFESU 2:14-16