Efe 2:14-16
Efe 2:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori on ni alafia wa, ẹniti o ti ṣe mejeji li ọ̀kan, ti o si ti wó ogiri ìkélé nì ti mbẹ lãrin; O si ti fi opin si ọta nì ninu ara rẹ̀, ani si ofin aṣẹ wọnni ti mbẹ ninu ilana; ki o le fi awọn mejeji dá ẹni titun kan ninu ara rẹ̀, ki o si ṣe ilaja, Ati ki o le mu awọn mejeji ba Ọlọrun làja ninu ara kan nipa agbelebu; o si ti pa iṣọta na kú nipa rẹ̀
Efe 2:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé Kristi yìí ni alaafia wa. Òun ni ó sọ àwọn tí wọ́n kọlà ati àwọn tí kò kọlà di ọ̀kan. Nígbà tí ó gbé ara eniyan wọ̀, ó wó ògiri ìkélé tí ó wà láàrin wọn tí wọ́n fi ń yan ara wọn lódì. Ó sọ òfin ati àwọn ìlànà ati àṣẹ di nǹkan yẹpẹrẹ, kí ó lè sọ àwọn mejeeji di ẹ̀dá titun kan náà ninu ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú alaafia wá sáàrin wọn. Ó làjà láàrin àwọn mejeeji, ó sọ wọ́n di ara kan lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa agbelebu. Ó ti mú odì yíyàn dópin lórí agbelebu.
Efe 2:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run.