ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:11-13

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:11-13 YCE

Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀.