ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:1-6

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:1-6 YCE

Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀: àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà; àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà. Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà, àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà. Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà; àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà. Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà; àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà. Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà; àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà.