Ó ní: “Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀; gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé. Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò, àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn; kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì, bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára. Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA, àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀. “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́. Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe, ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.
Kà DIUTARONOMI 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: DIUTARONOMI 32:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò