Deu 32:1-4
Deu 32:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní: “Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀; gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé. Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò, àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn; kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì, bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára. Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA, àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀. “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́. Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe, ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.
Deu 32:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fetísílẹ̀, Ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀; ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò, kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì, bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun, bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn. Èmi yóò kókìkí orúkọ OLúWA, Háà, ẹ yin títóbi Ọlọ́run wa! Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
Deu 32:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
FETISILẸ, ẹnyin ọrun, emi o si sọ̀rọ; si gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi, iwọ aiye: Ẹkọ́ mi yio ma kán bi ojò ohùn mi yio ma sẹ̀ bi ìri; bi òjo winiwini sara eweko titun, ati bi ọ̀wara òjo sara ewebẹ̀: Nitoriti emi o kokikí orukọ OLUWA kiri: ẹ fi ọlá fun Ọlọrun wa. Apata na, pipé ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọ̀na rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe, ododo ati otitọ li on.