DANIẸLI 4:28-30

DANIẸLI 4:28-30 YCE

Gbogbo nǹkan wọnyi sì ṣẹ mọ́ Nebukadinesari ọba lára. Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni, ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.”