ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4:29-31

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4:29-31 YCE

Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ. Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.” Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.