ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4

4
A Mú Peteru ati Johanu Wá siwaju Ìgbìmọ̀ Àwọn Juu
1Bí Peteru ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Johanu wà lọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn alufaa ati olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn Sadusi bá dé. 2Inú bí wọn nítorí wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan pé àwọn òkú yóo jí dìde. Wọ́n fi ajinde ti Jesu ṣe àpẹẹrẹ. 3Wọ́n bá mú wọn, wọ́n tì wọ́n mọ́lé títí di ọjọ́ keji, nítorí ilẹ̀ ti ṣú. 4Ṣugbọn ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́, iye wọn tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan.
5Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn ìjòyè ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin péjọ ní Jerusalẹmu. 6Anasi Olórí Alufaa ati Kayafa ati Johanu ati Alẹkisanderu ati àwọn ìdílé Olórí Alufaa wà níbẹ̀. 7Wọ́n mú Peteru ati Johanu wá siwaju ìgbìmọ̀. Wọ́n wá bi wọ́n pé, “Irú agbára wo ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe yìí? Orúkọ ta ni ẹ lò?”
8Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ wá fún Peteru ní agbára lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìjòyè láàrin àwọn eniyan ati ẹyin àgbààgbà, 9bí ẹ bá ń wádìí lónìí nípa iṣẹ́ rere tí a ṣe fún ọkunrin aláìsàn yìí, bí ẹ bá fẹ́ mọ bí ara rẹ̀ ti ṣe dá, 10ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo yín ati gbogbo eniyan Israẹli pé, ọkunrin yìí dúró níwájú yín pẹlu ara líle nítorí orúkọ Jesu Kristi ará Nasarẹti, ẹni tí ẹ kàn mọ́ agbelebu, tí Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. 11Jesu yìí ni#O. Daf 118:22
‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,
tí ó wá di òkúta pataki igun-ilé.’
12Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí orúkọ mìíràn tí a fi fún eniyan lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba eniyan là.”
13Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu. 14Wọ́n wo ọkunrin tí wọ́n mú lára dá tí ó dúró lọ́dọ̀ wọn, wọn kò sì mọ ohun tí wọn yóo sọ. 15Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ wá ń bi ara wọn pé, 16“Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀. 17Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.”
18Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́. 19Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò. 20Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.” 21Lẹ́yìn tí wọ́n tún halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n dá wọn sílẹ̀, nítorí wọn kò rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n níyà, nítorí àwọn eniyan. Gbogbo eniyan ni wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọrun fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. 22Ọkunrin tí wọn ṣe iṣẹ́ abàmì ìmúláradá yìí lára rẹ̀ ju ẹni ogoji ọdún lọ.
Àwọn Onigbagbọ Gbadura fún Ìgboyà
23Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn. 24Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,#Eks 20:11; Neh 9:6; O. Daf 146:6 25ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé,#O. Daf 2:1-2
‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí,
tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán?
26Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,
àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan,
láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’
27Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya,#a Luk 23:7-11; b Mat 27:1-2; Mak 15:1; Luk 23:1; Joh 18:28-29 28àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀. 29Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ. 30Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.”
31Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
Wọ́n Jọ Ní Ohun Gbogbo Ṣọ̀kan
32Ọkàn kan ati ẹ̀mí kan ni gbogbo àwùjọ àwọn onigbagbọ ní. Kò sí ẹnìkan ninu wọn tí ó dá àwọn nǹkan tirẹ̀ yà sọ́tọ̀, wọ́n jọ ní gbogbo nǹkan papọ̀ ni.#A. Apo 2:44-45 33Àwọn aposteli ń fi ẹ̀rí wọn hàn pẹlu agbára ńlá nípa ajinde Jesu Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan sì ń bọlá fún wọn. 34Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ṣe aláìní ohun kan láàrin wọn. Àwọn tí ó ní ilẹ̀ tabi ilé tà wọ́n, wọ́n mú owó tí wọ́n tà wọ́n wá, 35wọ́n dà á sílẹ̀ níwájú àwọn aposteli kí wọ́n lè pín in fún àwọn tí ó bá ṣe aláìní.
36Josẹfu, ọmọ ìdílé Lefi ará Kipru ẹni tí àwọn aposteli ń pè ní Banaba, (èyí ni “Ọmọ ìtùnú,”) 37ní ilẹ̀ kan. Ó tà á, ó sì mú owó rẹ̀ wá fún àwọn aposteli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa