ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 17:22-23

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 17:22-23 YCE

Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré. Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín.