Iṣe Apo 17:22-23
Iṣe Apo 17:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré. Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín.
Iṣe Apo 17:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí: fún ọlọ́run àìmọ̀. Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.
Iṣe Apo 17:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Paulu si dide duro larin Areopagu, o ni, Ẹnyin ará Ateni, mo woye pe li ohun gbogbo ẹ kun fun oniruru isin ju. Nitori bi mo ti nkọja lọ, ti mo wò ohun wọnni ti ẹnyin nsìn, mo si ri pẹpẹ kan ti a kọ akọle yi si, FUN ỌLỌRUN AIMỌ̀. Njẹ ẹniti ẹnyin nsìn li aimọ̀ on na li emi nsọ fun nyin.