ÀWỌN ỌBA KEJI 24
24
1Ní àkókò ìjọba Jehoiakimu ni Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu, Jehoiakimu sì di iranṣẹ rẹ̀ fún ọdún mẹta. Lẹ́yìn náà, ó pada lẹ́yìn Nebukadinesari, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí i. 2OLUWA bá rán àwọn ọmọ ogun Kalidea, ati ti Siria, ti Moabu, ati ti Amoni, láti pa Juda run bí ọ̀rọ̀ ti OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. 3Ìjìyà yìí dé bá Juda láti ọ̀dọ̀ OLUWA, láti pa wọ́n run kúrò níwájú rẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Manase ọba, 4ati nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀, nítorí tí ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgboro Jerusalẹmu, OLUWA kò ní dáríjì í.#Jer 25:1-30; Dan 1:1-2
5Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. 6Jehoiakimu kú, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
7Ọba Ijipti kò lè jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ mọ́, nítorí pé ọba Babiloni ti gba gbogbo ilẹ̀ ọba Ijipti láti odò Ijipti títí dé odò Yufurate.
Jehoiakini, Ọba Juda
(2Kron 36:9-10)
8Ẹni ọdún mejidinlogun ni Jehoiakini nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Nehuṣita, ọmọ Elinatani ará Jerusalẹmu. 9Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi baba rẹ̀.
10Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ ogun Nebukadinesari, ọba Babiloni, lọ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó tì í. 11Ní àkókò tí wọ́n dó ti ìlú náà ni Nebukadinesari ọba Babiloni lọ sibẹ. 12Ní ọdún kẹjọ tí ọba Babiloni jọba ni Jehoiakini ọba Juda jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba Babiloni, ó sì jọ̀wọ́ ìyá rẹ̀, àwọn iranṣẹ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pẹlu, ọba Babiloni bá kó wọn ní ìgbèkùn. 13Ó kó gbogbo àwọn ìṣúra ilé OLUWA ati àwọn ìṣúra tí ó wà ní ààfin. Gbogbo ohun èèlò wúrà tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA, tí Solomoni ọba Israẹli ṣe, ni ó gé sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ tẹ́lẹ̀. 14Ó kó gbogbo Jerusalẹmu ní ìgbèkùn; gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn akọni, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaarun (10,000), kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan ní ìlú náà, àfi àwọn talaka.#Jer 22:24-30; 24:1-10; 29:1-2
15Ó kó ọba Jehoiakini, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn aya rẹ̀, àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni. 16Ọba Babiloni kó ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn akọni ní ìgbèkùn ati ẹgbẹrun kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ alágbára tí wọ́n lè jagun.
17Ó fi Matanaya, arakunrin Jehoiakini jọba dípò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Sedekaya.#Isi 17:12 #Jer 37:1; Isi 17:13
Sedekaya, Ọba Juda
(2Kron 36:11-12; Jer 52:1-3a)
18Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó wà lórí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina.#Jer 27:1-22; 28:1-17 19Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jehoiakimu baba rẹ̀. 20Nítorí náà, OLUWA bínú sí Jerusalẹmu ati Juda; ó sì lé wọn kúrò níwájú rẹ̀.
Sedekaya sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.#Isi 17:15
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÀWỌN ỌBA KEJI 24: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010