ÀWỌN ỌBA KEJI 25

25
Ìṣubú Jerusalẹmu
(2Kron 36:13-21; Jer 52:3b-11)
1Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa ọdún kẹsan-an ìjọba rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ odi yí i ká.#Jer 21:1-10; 34:1-5; Isi 17:13 2Wọ́n dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya. 3Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn náà mú láàrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́. 4Nígbà náà ni wọ́n lu odi ìlú náà, ọba ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n lu odi ìlú náà, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin odi mejeeji lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, wọ́n sì gba ọ̀nà tí ó lọ sí Araba. 5Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa Sedekaya, wọ́n bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì túká kúrò lẹ́yìn rẹ̀. 6Ọwọ́ wọn tẹ Sedekaya, wọ́n bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ó sì dá ẹjọ́ fún un. 7Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni.#Isi 33:21 #Isi 12:13
Pípa Tẹmpili Run
(Jer 52:12-23)
8Ní ọjọ́ keje oṣù karun-un ọdún kọkandinlogun ìjọba Nebukadinesari, ọba Babiloni, Nebusaradani, tí ń ṣiṣẹ́ fún ọba Babiloni, tí ó sì tún jẹ́ olórí àwọn tí ń ṣọ́ Babiloni wá sí Jerusalẹmu. 9Ó sun ilé OLUWA níná, ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn ilé ńláńlá tí ó wà níbẹ̀ ni ó sì dáná sun.#1A. Ọba 9:8 10Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea, tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata. 11Nebusaradani kó àwọn tí wọ́n kù láàrin ìlú ati àwọn tí wọ́n sá tọ ọba Babiloni lọ, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn yòókù lọ sí ìgbèkùn. 12Ṣugbọn ó fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ láti máa tọ́jú ọgbà àjàrà ati láti máa dáko.
13Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada bàbà ńlá tí ó wà ninu ilé OLUWA pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà wọn lọ sí Babiloni. 14Wọ́n kó àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀kọ̀, àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná lẹ́nu àtùpà, àwọn àwo turari ati àwọn ohun èlò bàbà tí wọ́n máa ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA. 15Bákan náà, wọ́n kó àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwo kòtò, gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti wúrà ati fadaka, ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ. 16Bàbà tí Solomoni fi ṣe àwọn òpó mejeeji, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kọjá wíwọ̀n. 17Gíga ọ̀kan ninu àwọn òpó náà jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, ọpọ́n idẹ tí ó wà lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta, wọ́n fi bàbà ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati pomegiranate yí ọpọ́n náà ká, òpó keji sì dàbí ti àkọ́kọ́ pẹlu ẹ̀wọ̀n bàbà náà.#a 1A. Ọba 7:15-26; 2Kron 3:15-17 b 1A. Ọba 7:23-26; 2Kron 4:2-5 #1A. Ọba 7:45; 2Kron 4:16
A Kó Àwọn Eniyan Juda Lọ sí Babiloni
(Jer 52:24-27)
18Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraya olórí alufaa, ati Sefanaya igbákejì alufaa, ati àwọn aṣọ́nà mẹta. 19Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà. 20Nebusaradani kó gbogbo wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila. 21Ọba Babiloni lù wọ́n, ó sì pa wọ́n sórí ilẹ̀ Hamati.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe kó Juda ní ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.
Gedalaya, Gomina Juda
(Jer 40:7-9; 41:1-3)
22Nebukadinesari ọba Babiloni yan Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani ní gomina lórí àwọn tí wọ́n kù ní ilẹ̀ Juda. 23Nígbà tí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu ṣe Gomina ní ilẹ̀ Juda, àwọn pẹlu àwọn eniyan wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n wá ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraya, ọmọ Tanhumeti, ará Netofa, ati Jaasanaya, ọmọ ará Maakati. 24Gedalaya bá búra fún wọn, ó ní: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù nítorí àwọn olórí Kalidea, ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.”#Jer 40:7-9
25Ṣugbọn ní oṣù keje Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, ọmọ Eliṣama, láti ìdílé ọba, pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá dojú kọ Gedalaya, wọ́n sì pa òun, ati àwọn Juu ati àwọn ará Kalidea tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Misipa. 26Ni gbogbo wọn, àtọmọdé, àtàgbà, ati àwọn olórí ogun bá gbéra, wọ́n kó lọ sí Ijipti, nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea bà wọ́n.#Jer 41:1-3 #Jer 43:5-7
A Dá Jehoiakini Sílẹ̀ kúrò Ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
(Jer 52:31-34)
27Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí wọ́n ti mú Jehoiakini ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kejila ọdún náà, Efilimerodaki, ọba Babiloni, gbé ọ̀rọ̀ Jehoiakini yẹ̀wò, ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀ kúrò ní ẹ̀wọ̀n. 28Ó bá a sọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ. 29Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 30Ọba Babiloni rí i pé òun ń pèsè ohun tí ó nílò ní ojoojumọ fún un, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KEJI 25: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀