KỌRINTI KEJI 5:1-4

KỌRINTI KEJI 5:1-4 YCE

Nítorí a mọ̀ pé bí àgọ́ ara tí a fi ṣe ilé ní ayé yìí bá wó, a ní ilé kan lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí yóo wà lọ́run títí laelae. Nítorí ninu àgọ́ ara yìí à ń kérora, à ń tiraka láti gbé ilé wa ti ọ̀run wọ̀. A ní ìrètí pé bí a bá gbé e wọ̀, a kò ní bá ara wa níhòòhò. Àwa tí a wà ninu àgọ́ ara yìí ń kérora nítorí pé ara ń ni wá, kò jẹ́ pé a fẹ́ bọ́ àgọ́ ara yìí sílẹ̀, ṣugbọn àgọ́ ara yìí ni a fẹ́ gbé ara titun wọ̀ lé, kí ara ìyè lè gbé ara ikú mì.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú KỌRINTI KEJI 5:1-4