II. Kor 5:1-4
II. Kor 5:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI awa mọ̀ pe, bi ile agọ́ wa ti aiye bá wó, awa ni ile kan lati ọdọ Ọlọrun, ile ti a kò fi ọwọ́ kọ́, ti aiyeraiye ninu awọn ọrun. Nitori nitõtọ awa nkerora ninu eyi, awa si nfẹ gidigidi lati fi ile wa lati ọrun wá wọ̀ wa: Bi o ba ṣepe a ti wọ̀ wa li aṣọ, a kì yio bá wa ni ìhoho. Nitori awa ti mbẹ ninu agọ́ yi nkerora nitõtọ, ẹrù npa wa: kì iṣe nitori ti awa nfẹ ijẹ alaiwọ̀ṣọ, ṣugbọn ki a le wọ̀ wa li aṣọ, ki iyè ki o le gbé ara kiku mì.
II. Kor 5:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí a mọ̀ pé bí àgọ́ ara tí a fi ṣe ilé ní ayé yìí bá wó, a ní ilé kan lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí yóo wà lọ́run títí laelae. Nítorí ninu àgọ́ ara yìí à ń kérora, à ń tiraka láti gbé ilé wa ti ọ̀run wọ̀. A ní ìrètí pé bí a bá gbé e wọ̀, a kò ní bá ara wa níhòòhò. Àwa tí a wà ninu àgọ́ ara yìí ń kérora nítorí pé ara ń ni wá, kò jẹ́ pé a fẹ́ bọ́ àgọ́ ara yìí sílẹ̀, ṣugbọn àgọ́ ara yìí ni a fẹ́ gbé ara titun wọ̀ lé, kí ara ìyè lè gbé ara ikú mì.
II. Kor 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì.