Ó hàn gbangba pé ẹ̀yin ni ìwé tí Kristi kọ, tí ó fi rán wa. Kì í ṣe irú èyí tí wọ́n fi yíǹkì kọ, Ẹ̀mí Ọlọrun alààyè ni wọ́n fi kọ ọ́. Kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sí orí òkúta; ọkàn eniyan ni wọ́n kọ ọ́ sí. A lè sọ èyí nítorí a ní igbẹkẹle ninu Ọlọrun nípa Kristi. Kì í ṣe pé a ní agbára tó ninu ara wa, tabi pé a ti lè ṣe nǹkankan fúnra wa. Ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti ní gbogbo nǹkan ní ànító. Ọlọrun ni ó mú kí á lè jẹ́ iranṣẹ ti majẹmu titun, tí kì í ṣe ti òfin tí a kọ bíkòṣe ti Ẹ̀mí. Nítorí ikú ni òfin tí a kọ sílẹ̀ ń mú wá, ṣugbọn majẹmu ti Ẹ̀mí ń sọ eniyan di alààyè. Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, báwo ni iranṣẹ ti Ẹ̀mí yóo ti lógo tó? Bí iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa lẹ́bi bá lógo, báwo ni iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa láre yóo ti lógo tó? Àní ohun tí ó lógo tẹ́lẹ̀ kò tún lógo mọ́ nítorí ohun mìíràn tí ògo tirẹ̀ ta á yọ. Nítorí bí ohun tí yóo pada di asán bá lógo, mélòó-mélòó ni ti ohun tí yóo wà títí laelae? Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní irú ìrètí yìí, a ń fi ìgboyà pupọ sọ̀rọ̀. A kò dàbí Mose tí ó fi aṣọ bojú rẹ̀, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà rí ògo ojú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ògo tíí ṣá ni. Ṣugbọn ọkàn wọn ti le, nítorí títí di ọjọ́ òní, aṣọ náà ni ó ń bo ọkàn wọn nígbà tí wọn bá ń ka ìwé majẹmu àtijọ́. Wọn kò mú aṣọ náà kúrò, nítorí nípasẹ̀ Kristi ni majẹmu àtijọ́ fi di asán. Ṣugbọn títí di ọjọ́ òní, nígbàkúùgbà tí wọn bá ń ka Òfin Mose, aṣọ a máa bo ọkàn wọn. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa Mose, “Nígbàkúùgbà tí ó bá yipada sí Oluwa, a mú aṣọ kúrò lójú.” Ǹjẹ́ Oluwa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni Ẹ̀mí Mímọ́. Níbikíbi tí Ẹ̀mí Oluwa bá wà, òmìnira wà níbẹ̀. Kò sí aṣọ tí ó bò wá lójú. Ojú gbogbo wa ń fi ògo Oluwa hàn bí ìgbà tí eniyan ń wo ojú rẹ̀ ninu dígí. À ń pa wá dà sí ògo mìíràn tí ó tayọ ti àkọ́kọ́. Èyí jẹ́ iṣẹ́ Oluwa tí í ṣe Ẹ̀mí.
Kà KỌRINTI KEJI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KỌRINTI KEJI 3:3-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò