KRONIKA KEJI 31:20-21

KRONIKA KEJI 31:20-21 YCE

Jákèjádò Juda ni Hesekaya ti ṣe ètò yìí, ó ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òtítọ́ lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òfin ati àṣẹ Ọlọ́run, ati wíwá tí ó wá ojurere Ọlọrun, gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe tọkàntọkàn, ó sì dára fún un.