II. Kro 31:20-21
II. Kro 31:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi ni Hesekiah si ṣe ni gbogbo Juda, o si ṣe eyiti o dara, ti o si tọ́, ti o si ṣe otitọ, niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀. Ati ninu gbogbo iṣẹ ti o bẹ̀rẹ ninu iṣẹ-ìsin ile Ọlọrun, ati ninu ofin, ati ni aṣẹ, lati wá Ọlọrun, o fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe e, o si ṣe rere.
II. Kro 31:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Jákèjádò Juda ni Hesekaya ti ṣe ètò yìí, ó ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òtítọ́ lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òfin ati àṣẹ Ọlọ́run, ati wíwá tí ó wá ojurere Ọlọrun, gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe tọkàntọkàn, ó sì dára fún un.
II. Kro 31:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni Hesekiah ṣe jákèjádò Juda, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀. Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé ní ti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere.