SAMUẸLI KINNI 24:4-8

SAMUẸLI KINNI 24:4-8 YCE

Àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Dafidi sọ fún un pé, “Òní gan-an ni ọjọ́ tí OLUWA ti sọ fún ọ nípa rẹ̀, pé òun yóo fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o lè ṣe é bí ó ti wù ọ́.” Dafidi bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Saulu wà, ó sì gé etí aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọkàn Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi nítorí pé ó gé etí aṣọ Saulu. Ó sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Kí OLUWA pa mí mọ́ kúrò ninu ṣíṣe ibi sí oluwa mi, ẹni tí OLUWA ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba. N kò gbọdọ̀ fọwọ́ mi kàn án, nítorí ẹni àmì òróró OLUWA ni.” Nípa báyìí Dafidi dá àwọn eniyan rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọ́n pa Saulu. Saulu jáde ninu ihò náà, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Dafidi jáde, ó pè é, ó ní, “Olúwa mi ọba,” bí Saulu ti wo ẹ̀yìn ni Dafidi dojúbolẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un.