I. Sam 24:4-8
I. Sam 24:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu. O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu. On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni. Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ. Dafidi si dide lẹhin na, o si jade kuro ninu iho na, o si kọ si Saulu pe, Oluwa mi, ọba. Saulu si wo ẹhìn rẹ̀, Dafidi si doju rẹ̀ bo ilẹ, o si tẹriba fun u.
I. Sam 24:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Dafidi sọ fún un pé, “Òní gan-an ni ọjọ́ tí OLUWA ti sọ fún ọ nípa rẹ̀, pé òun yóo fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o lè ṣe é bí ó ti wù ọ́.” Dafidi bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Saulu wà, ó sì gé etí aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọkàn Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi nítorí pé ó gé etí aṣọ Saulu. Ó sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Kí OLUWA pa mí mọ́ kúrò ninu ṣíṣe ibi sí oluwa mi, ẹni tí OLUWA ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba. N kò gbọdọ̀ fọwọ́ mi kàn án, nítorí ẹni àmì òróró OLUWA ni.” Nípa báyìí Dafidi dá àwọn eniyan rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọ́n pa Saulu. Saulu jáde ninu ihò náà, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Dafidi jáde, ó pè é, ó ní, “Olúwa mi ọba,” bí Saulu ti wo ẹ̀yìn ni Dafidi dojúbolẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un.
I. Sam 24:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí OLúWA wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu. Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ OLúWA wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi ààmì òróró OLúWA yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni ààmì òróró OLúWA ni.” Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un.