KỌRINTI KINNI 7:25-40

KỌRINTI KINNI 7:25-40 YCE

N kò ní àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Oluwa láti pa fún àwọn wundia. Ṣugbọn mò ń sọ ohun tí mo rò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Oluwa ti ṣàánú fún, tí eniyan sì lè gbẹ́kẹ̀lé. Mo rò pé ohun tí ó dára ni pé kí eniyan má ṣe kúrò ní ipò tí ó wà, nítorí àkókò ìpọ́njú ni àkókò yìí. Bí o bá ti gbé iyawo, má ṣe wá ọ̀nà láti kọ aya rẹ. Bí o bá sì ti kọ aya rẹ, má ṣe wá ọ̀nà láti tún gbé iyawo. Ṣugbọn bí o bá gbeyawo, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Bí wundia náà bá sì lọ́kọ, kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn irú àwọn bẹ́ẹ̀ yóo ní ìpọ́njú ní ti ara. Bẹ́ẹ̀ ni n kò sì fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ̀yin ará, ohun tí mò ń sọ nìyí. Àkókò tí ó kù fún wa kò gùn. Ninu èyí tí ó kù, kí àwọn tí wọ́n ní iyawo ṣe bí ẹni pé wọn kò ní. Kí àwọn tí ń sunkún máa ṣe bí ẹni pé wọn kò sunkún. Kí àwọn tí ń yọ̀ máa ṣe bí ẹni pé wọn kò yọ̀. Kí àwọn tí ń ra nǹkan máa ṣe bí ẹni pé kì í ṣe tiwọn ni ohun tí wọ́n ní. Kí àwọn tí ń lo dúkìá ayé máa lò ó láì dara dé e patapata. Nítorí bí ayé yìí ti ń rí yìí, ó ń kọjá lọ. Ṣugbọn mo fẹ́ rí i pé ẹ kò ní ìpayà kan tí yóo mú ọkàn yín wúwo. Ẹni tí kò bá ní iyawo yóo máa páyà nípa nǹkan Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó wu Oluwa. Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbeyawo yóo máa páyà nípa nǹkan ti ayé yìí, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ iyawo rẹ̀ lọ́rùn; ọkàn rẹ̀ yóo pín sí meji. Obinrin tí kò bá lọ́kọ tabi obinrin tí ó bá jẹ́ wundia yóo máa páyà nípa nǹkan ti Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà tí yóo fi ya ara ati ọkàn rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Oluwa. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ní ọkọ yóo máa páyà nípa àwọn nǹkan ayé, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. Fún ire ara yín ni mo fi ń sọ èyí fun yín, kì í ṣe láti dín òmìnira yín kù. Ohun tí mò ń fẹ́ ni pé kí ẹ lè gbé irú ìgbé-ayé tí ó yẹ, kí ẹ lè fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ Oluwa, láìwo ọ̀tún tabi òsì. Ṣugbọn bí ọkunrin kan bá rò pé òun ń ṣe ohun tí kò tọ́ pẹlu wundia àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí wundia náà bá ti dàgbà tó, tí ọkunrin náà kò bá lè mú ara dúró, kí ó ṣe igbeyawo bí ó bá fẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Kí wọ́n ṣe igbeyawo. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pinnu ninu ọkàn rẹ̀, tí kò sí ìdí tí ó fi gbọdọ̀ ṣe igbeyawo, bí ó bá lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun yóo jẹ́ kí wundia òun wà bí ó ti wà, nǹkan dáradára ni ó ṣe. Ní gbolohun kan, ẹni tí ó bá gbé wundia rẹ̀ ní iyawo kò ṣe nǹkan burúkú. Ṣugbọn ẹni tí kò bá gbé e ní iyawo ni ó ṣe ohun tí ó dára jùlọ. A ti so obinrin pọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti tún ní ọkọ mìíràn tí ó bá fẹ́. Ṣugbọn onigbagbọ nìkan ní ó lè fẹ́. Ṣugbọn mo rò pé ó sàn fún un pupọ jùlọ tí ó bá dá wà. Mo sì rò pé èmi náà ní Ẹ̀mí Ọlọrun.