I. Kor 7:25-40

I. Kor 7:25-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn nipa ti awọn wundia, emi kò ni aṣẹ Oluwa: ṣugbọn mo fun nyin ni imọran bi ẹniti o ri ãnu Oluwa gbà lati jẹ olododo. Nitorina mo rò pe eyi dara nitori wahalà isisiyi, eyini ni pe, o dara fun enia ki o wà bẹ̃. A ti dè ọ mọ́ aya ri bi? máṣe wá ọ̀na lati tú kuro. A ti tú ọ kuro lọwọ aya bi? máṣe wá aya ni. Ṣugbọn bi iwọ ba si gbeyawo, iwọ kò dẹṣẹ: bi a ba si gbé wundia ni iyawo, on kò dẹṣẹ. Ṣugbọn irú awọn wọnni yio ni wahalà nipa ti ara: ṣugbọn mo dá nyin si. Ṣugbọn eyi ni mo wi, ará, pe kukuru li akokò: lati isisiyi lọ pe ki awọn ti o li aya ki o dabi ẹnipe nwọn kò ni rí; Ati awọn ti nsọkun, bi ẹ́nipe nwọn kò sọkun rí; ati awọn ti nyọ̀, bi ẹnipe nwọn kò yọ̀ rí; ati awọn ti nrà, bi ẹnipe nwọn kò ni rí; Ati awọn ti nlò ohun aiye yi bi ẹniti kò ṣaṣeju: nitori aṣa aiye yi nkọja lọ. Ṣugbọn emi nfẹ ki ẹnyin ki o wà laiṣe aniyàn. Ẹniti kò gbeyawo ama tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, bi yio ti ṣe le wù Oluwa: Ṣugbọn ẹniti o gbeyawo ama ṣe itọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù aya rẹ̀. Iyatọ si wà pẹlu larin obinrin ti a gbe ni iyawo ati wundia. Obinrin ti a kò gbe ni iyawo a mã tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, ki on ki o le jẹ mimọ́ li ara ati li ẹmí: ṣugbọn ẹniti a gbé ni iyawo a ma tọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù ọkọ rẹ̀. Eyi ni mo si nwi fun ère ara nyin; kì iṣe lati dẹkun fun nyin, ṣugbọn nitori eyi ti o tọ́, ati ki ẹnyin ki o le mã sin Oluwa laisi ìyapa-ọkàn. Ṣugbọn bi ẹnikan ba rò pe on kò ṣe ohun ti o yẹ si wundia ọmọbinrin rẹ̀, bi o ba ti di obinrin, bi o ba si tọ bẹ̃, jẹ ki o ṣe bi o ti fẹ, on kò dẹṣẹ: jẹ ki nwọn gbé iyawo. Ṣugbọn ẹniti o duro ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, ti ko ni aigbọdọ máṣe, ṣugbọn ti o li agbara lori ifẹ ara rẹ̀, ti o si ti pinnu li ọkàn rẹ̀ pe, on o pa wundia ọmọbinrin on mọ́, yio ṣe rere. Bẹ̃ si li ẹniti o fi wundia ọmọbinrin funni ni igbeyawo, o ṣe rere: ṣugbọn ẹniti kò fi funni ni igbeyawo ṣe rere jù. A fi ofin dè obinrin niwọn igbati ọkọ rẹ̀ ba wà lãye; ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o di omnira lati ba ẹnikẹni ti o wù u gbeyawo; kìki ninu Oluwa. Ṣugbọn gẹgẹ bi imọ̀ mi, alabukun-fun julọ ni bi on ba duro bẹ̃: emi pẹlu si rò pe mo li Ẹmi Ọlọrun.

I. Kor 7:25-40 Yoruba Bible (YCE)

N kò ní àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Oluwa láti pa fún àwọn wundia. Ṣugbọn mò ń sọ ohun tí mo rò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Oluwa ti ṣàánú fún, tí eniyan sì lè gbẹ́kẹ̀lé. Mo rò pé ohun tí ó dára ni pé kí eniyan má ṣe kúrò ní ipò tí ó wà, nítorí àkókò ìpọ́njú ni àkókò yìí. Bí o bá ti gbé iyawo, má ṣe wá ọ̀nà láti kọ aya rẹ. Bí o bá sì ti kọ aya rẹ, má ṣe wá ọ̀nà láti tún gbé iyawo. Ṣugbọn bí o bá gbeyawo, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Bí wundia náà bá sì lọ́kọ, kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn irú àwọn bẹ́ẹ̀ yóo ní ìpọ́njú ní ti ara. Bẹ́ẹ̀ ni n kò sì fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ̀yin ará, ohun tí mò ń sọ nìyí. Àkókò tí ó kù fún wa kò gùn. Ninu èyí tí ó kù, kí àwọn tí wọ́n ní iyawo ṣe bí ẹni pé wọn kò ní. Kí àwọn tí ń sunkún máa ṣe bí ẹni pé wọn kò sunkún. Kí àwọn tí ń yọ̀ máa ṣe bí ẹni pé wọn kò yọ̀. Kí àwọn tí ń ra nǹkan máa ṣe bí ẹni pé kì í ṣe tiwọn ni ohun tí wọ́n ní. Kí àwọn tí ń lo dúkìá ayé máa lò ó láì dara dé e patapata. Nítorí bí ayé yìí ti ń rí yìí, ó ń kọjá lọ. Ṣugbọn mo fẹ́ rí i pé ẹ kò ní ìpayà kan tí yóo mú ọkàn yín wúwo. Ẹni tí kò bá ní iyawo yóo máa páyà nípa nǹkan Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó wu Oluwa. Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbeyawo yóo máa páyà nípa nǹkan ti ayé yìí, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ iyawo rẹ̀ lọ́rùn; ọkàn rẹ̀ yóo pín sí meji. Obinrin tí kò bá lọ́kọ tabi obinrin tí ó bá jẹ́ wundia yóo máa páyà nípa nǹkan ti Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà tí yóo fi ya ara ati ọkàn rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Oluwa. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ní ọkọ yóo máa páyà nípa àwọn nǹkan ayé, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. Fún ire ara yín ni mo fi ń sọ èyí fun yín, kì í ṣe láti dín òmìnira yín kù. Ohun tí mò ń fẹ́ ni pé kí ẹ lè gbé irú ìgbé-ayé tí ó yẹ, kí ẹ lè fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ Oluwa, láìwo ọ̀tún tabi òsì. Ṣugbọn bí ọkunrin kan bá rò pé òun ń ṣe ohun tí kò tọ́ pẹlu wundia àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí wundia náà bá ti dàgbà tó, tí ọkunrin náà kò bá lè mú ara dúró, kí ó ṣe igbeyawo bí ó bá fẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Kí wọ́n ṣe igbeyawo. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pinnu ninu ọkàn rẹ̀, tí kò sí ìdí tí ó fi gbọdọ̀ ṣe igbeyawo, bí ó bá lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun yóo jẹ́ kí wundia òun wà bí ó ti wà, nǹkan dáradára ni ó ṣe. Ní gbolohun kan, ẹni tí ó bá gbé wundia rẹ̀ ní iyawo kò ṣe nǹkan burúkú. Ṣugbọn ẹni tí kò bá gbé e ní iyawo ni ó ṣe ohun tí ó dára jùlọ. A ti so obinrin pọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti tún ní ọkọ mìíràn tí ó bá fẹ́. Ṣugbọn onigbagbọ nìkan ní ó lè fẹ́. Ṣugbọn mo rò pé ó sàn fún un pupọ jùlọ tí ó bá dá wà. Mo sì rò pé èmi náà ní Ẹ̀mí Ọlọrun.

I. Kor 7:25-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá: èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo. Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsin yìí, èyí nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí o ṣe wà. Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹlẹ́rìí láti fẹ́ ìyàwó. Ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí o kò bá sì tí ìgbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáré láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákokò yìí. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara: ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí. Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí; àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí, àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ. Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúńdíá rẹ̀ ti ìpòùngbẹ rẹ si pọ si, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́ṣẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lórí ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúńdíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere. Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúńdíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jùlọ. A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láààyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa. Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́. Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.