KRONIKA KINNI 4

4
Ìran Juda
1Àwọn ọmọ Juda ni: Peresi, Hesironi, Kami, Huri, ati Ṣobali. 2Ṣobali ni ó bí Reaaya. Reaaya sì bí Jahati. Jahati ni baba Ahumai ati Lahadi. Àwọn ni ìdílé àwọn tí ń gbé Sora.
3Àwọn ọmọ Etamu ni: Jesireeli, Iṣima, ati Idibaṣi. Orúkọ arabinrin wọn ni Haseleliponi. 4Penueli ni baba Gedori. Eseri bí Huṣa. Àwọn ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efurata, tí ó jẹ́ baba Bẹtilẹhẹmu.
5Aṣuri, baba Tekoa, ní aya meji: Hela ati Naara. 6Naara bí ọmọ mẹrin fún un: Ahusamu, Heferi, Temeni, ati Haahaṣitari. 7Hela bí ọmọ mẹta fún un: Sereti, Iṣari, ati Etinani.
8Kosi ni baba Anubi ati Sobeba. Òun ni baba ńlá àwọn ìdílé Ahaheli, ọmọ Harumu.
9Ọkunrin kan, tí à ń pè ní Jabesi, jẹ́ eniyan pataki ju àwọn arakunrin rẹ̀ lọ. Ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ yìí nítorí ìrora pupọ tí ó ní nígbà tí ó bí i. 10Jabesi gbadura sí Ọlọrun Israẹli pé, “Ọlọrun jọ̀wọ́ bukun mi, sì jẹ́ kí ilẹ̀ ìní mi pọ̀ sí i. Wà pẹlu mi, pa mí mọ́ kúrò ninu ewu, má jẹ́ kí jamba ṣe mí!” Ọlọrun sì ṣe ohun tí ó fẹ́ fún un.
Àwọn Ìdílé Yòókù
11Kelubu, arakunrin Ṣuha, ni baba Mehiri, Mehiri ni baba Eṣitoni. 12Eṣitoni yìí ni ó bí Betirafa, Pasea ati Tẹhina. Tẹhina sì ni baba Irinahaṣi. Àwọn ni wọ́n ń gbé Reka.
13Kenasi bí ọmọ meji: Otinieli ati Seraaya. Otinieli náà bí Hatati ati Meonotai. 14Meonotai ni baba Ofira.
Seraaya sì ni baba Joabu, baba àwọn ará Geharaṣimu, ìlú àwọn oníṣọ̀nà. Àwọn ni wọ́n tẹ gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ dó.
15Kalebu, ọmọ Jefune, bí ọmọ mẹta: Iru, Ela, ati Naamu. Ela ni ó bí Kenasi.
16Jehaleli sì ni baba Sifi, Sifa, Tiria, ati Asareli.
17Ẹsira bí Jeteri, Meredi, Eferi, ati Jaloni. Meredi fẹ́ Bitia, ọmọbinrin Farao. Wọ́n bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu ati ọmọkunrin meji: Ṣamai ati Iṣiba. 18Iṣiba ni baba Eṣitemoa. Meredi tún ní iyawo mìíràn, òun jẹ́ ará Juda, ó bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeredi, baba Gedori, Heberi baba Soko, ati Jekutieli, baba Sanoa.
19Hodia fẹ́ arabinrin Nahamu, àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ṣẹ ẹ̀yà Garimi, tí wọn ń gbé ìlú Keila sílẹ̀, ati àwọn ìran Maakati tí wọn ń gbé ìlú Eṣitemoa. 20Simoni ni baba Aminoni, Rina, Benhanani ati Tiloni. Iṣi sì ni baba Soheti ati Benisoheti.
Àwọn Ìran Ṣela
21Ṣela, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Juda, ni baba Eri, baba Leka. Laada ni baba Mareṣa, ati ìdílé àwọn tí wọ́n ń hun aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun ní Beti Aṣibea 22ati Jokimu, ati àwọn ará ìlú Koseba, Joaṣi ati Sarafu, tí wọ́n fi ìgbà kan jẹ́ alákòóso ní Moabu, tí wọ́n sì pada sí Bẹtilẹhẹmu. (Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ti àtijọ́.) 23Wọ́n jẹ́ amọ̀kòkò ní ààfin ọba, wọ́n sì ń gbé ìlú Netaimu ati Gedera.
Àwọn Ìran Simeoni
24Simeoni ni baba Nemueli, Jamini, Jaribu, Sera, ati Ṣaulu. 25Ṣaulu bí Ṣalumu, Ṣalumu bí Mibisamu, Mibisamu sì bí Miṣima. 26Àwọn ọmọ Miṣima nìyí: Hamueli, Sakuri, ati Ṣimei. 27Ṣimei bí ọmọkunrin mẹrindinlogun ati ọmọbinrin mẹfa. Ṣugbọn àwọn arakunrin rẹ̀ kò bí ọmọ pupọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà rẹ̀ kò pọ̀ bí ẹ̀yà Juda.
28Àwọn ìran Simeoni ní ń gbé àwọn ìlú wọnyi títí di àkókò ọba Dafidi: Beeriṣeba, Molada, ati Hasariṣuali. 29Biliha, Esemu, ati Toladi; 30Betueli, Horima, ati Sikilagi; 31Beti Makabotu, Hasasusimu, Betibiri, ati Ṣaaraimu. 32Àwọn ìletò wọn ni: Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni ati Aṣani, 33àwọn ìlú marun-un pẹlu àwọn ìgbèríko tí ó yí wọn ká títí dé ìlú Baali. Àwọn agbègbè náà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ní àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.#Joṣ 19:2-8
34Meṣobabu, Jamileki, ati Joṣa, jẹ́ ọmọ Amasaya; 35Joẹli, ati Jehu, ọmọ Joṣibaya, ọmọ Seraaya, ọmọ Asieli. 36Elioenai, Jaakoba, ati Jeṣohaya; Asaya, Adieli, Jesimieli ati Bẹnaya; 37Sisa, ọmọ Ṣifi, ọmọ Aloni, ọmọ Jedaaya, ọmọ Ṣimiri, ọmọ Ṣemaaya. 38Gbogbo wọn jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, ìdílé àwọn baba wọn sì pọ̀ lọpọlọpọ. 39Wọ́n rìn títí dé ẹnubodè Gedori, ní apá ìlà oòrùn àfonífojì, láti wá koríko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. 40Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí ilẹ̀ tí ó ní koríko, tí ó sì dára fún àwọn ẹran wọn. Ilẹ̀ náà tẹ́jú, ó parọ́rọ́, alaafia sì wà níbẹ̀; àwọn ọmọ Hamu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.
41Nígbà tí Hesekaya, ọba Juda wà lórí oyè, àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi lọ sí Meuni, wọ́n ba àgọ́ àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ jẹ́, wọ́n pa wọ́n run títí di òní, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilẹ̀ tiwọn, nítorí pé koríko tútù pọ̀ níbẹ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. 42Ẹẹdẹgbẹta (500) ninu àwọn eniyan Simeoni ló lọ sí òkè Seiri; àwọn olórí wọn ni: Pelataya, Nearaya, Refaaya, ati Usieli, lára àwọn ọmọ Iṣi. 43Wọ́n pa àwọn ọmọ Amaleki yòókù tí wọ́n sá àsálà, wọ́n sì ń gbé orí ilẹ̀ wọn títí di òní olónìí.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀