KRONIKA KINNI 5
5
Ìran Reubẹni
1Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí. 2Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà Juda di ẹ̀yà tí ó lágbára ju gbogbo ẹ̀yà yòókù lọ, tí wọ́n sì ń jọba lórí wọn, sibẹsibẹ ipò àkọ́bí jẹ́ ti àwọn ọmọ Josẹfu). 3Àwọn ọmọ Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu, ni: Hanoku, Palu, Hesironi ati Kami. 4Joẹli ni ó bí Ṣemaya, Ṣemaya bí Gogu, Gogu bí Ṣimei; 5Ṣimei bí Mika, Mika bí Reaaya, Reaaya bí Baali; 6Baali bí Beera, tí Tigilati Pileseri ọba Asiria mú lẹ́rú lọ; Beera yìí jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà Reubẹni.#Jẹn 35:22; 49:3-4 #Jẹn 49:8-10 #2A. Ọba 15:29
7Àwọn arakunrin rẹ̀ ní ìdílé wọn, nígbà tí a kọ àkọsílẹ̀, ìran wọn nìyí: olórí wọn ni Jeieli, ati Sakaraya, ati 8Bela, ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli, tí wọn ń gbé Aroeri títí dé Nebo ati Baali Meoni. 9Ilẹ̀ wọn lọ ní apá ìlà oòrùn títí dé àtiwọ aṣálẹ̀, ati títí dé odò Yufurate, nítorí pé ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ ní ilẹ̀ Gileadi.
10Ní àkókò ọba Saulu, àwọn ẹ̀yà Reubẹni wọnyi gbógun ti àwọn ará Hagiriti, wọ́n pa wọ́n run, wọ́n gba ilẹ̀ wọn tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Gileadi.
Àwọn Ìran Gadi
11Àwọn ẹ̀yà Gadi ń gbé òdìkejì ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀ Baṣani, títí dé Saleka: 12Joẹli ni olórí wọn ní ilẹ̀ Baṣani, Safamu ni igbá keji rẹ̀; àwọn olórí yòókù ni Janai ati Ṣafati. 13Àwọn arakunrin wọn ní ìdílé wọn ni: Mikaeli, Meṣulamu, ati Ṣeba; Jorai, Jakani, Sia, ati Eberi, gbogbo wọn jẹ́ meje. 14Àwọn ni ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jahido, ọmọ Busi. 15Ahi, ọmọ Abidieli, ọmọ Guni ni olórí ìdílé baba wọn; 16wọ́n ń gbé Gileadi, Baṣani ati àwọn ìlú tí wọ́n yí Baṣani ká, ati ní gbogbo ilẹ̀ pápá Ṣaroni. 17A kọ àkọsílẹ̀ wọn ní àkókò Jotamu, ọba Juda, ati ní àkókò Jeroboamu ọba Israẹli.
Àwọn Ọmọ Ogun Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn
18Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, àwọn ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ní ẹgbaa mejilelogun ati ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (44,760) akọni ọmọ ogun tí wọ́n ń lo asà, idà, ọfà ati ọrun lójú ogun, tí wọ́n gbáradì fún ogun. 19Wọ́n gbógun ti àwọn ará Hagiriti, Jeturi, Nafiṣi ati Nodabu. 20Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e. 21Àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó lójú ogun nìwọ̀nyí: ẹgbaa mẹẹdọgbọn (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ mejila lé ẹgbaarun (250,000) aguntan, ati ẹgbaa (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; wọ́n sì kó ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọkunrin lẹ́rú. 22Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n pa, nítorí pé Ọlọrun ni ó jà fún wọn; wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn títí tí àwọn ará Asiria fi kó wọn lẹ́rú.
Ìdajì Ẹ̀yà Manase Tí Ń gbé Ìhà Ìlà Oòrùn
23Ìdajì ẹ̀yà Manase ń gbé Baṣani, wọ́n pọ̀ pupọ; wọ́n tàn ká títí dé Baali Herimoni, Seniri, ati òkè Herimoni. 24Àwọn Olórí ìdílé wọn nìwọ̀nyí: Eferi, Iṣi, Elieli, ati Asirieli; Jeremaya, Hodafaya ati Jahidieli, akikanju jagunjagun ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ olókìkí ati olórí ní ilé baba wọn.
A Kó Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Lẹ́rú Lọ
25Ṣugbọn àwọn ẹ̀yà náà ṣẹ Ọlọrun baba wọn, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa tí àwọn tí Ọlọrun parun nítorí wọn ń bọ. 26Nítorí náà, Ọlọrun ta Pulu ọba Asiria ati Tigilati Pileseri ọba Asiria, nídìí láti gbógun ti ilẹ̀ náà; wọ́n bá kó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọn ń gbé ìhà ìlà oòrùn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ Hala, Habori, Hara, ati ẹ̀bá odò Gosani títí di òní olónìí.#(a) 2A. Ọba 15:19 (b) 2A. Ọba 15:29 (d) 2A. Ọba 17:6
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KINNI 5: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010