Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni; Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri.
Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á. Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera.
Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli. Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada. Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀.
Etani ni ó bí Asaraya.
Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai.
Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda, Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi, Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese.
Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea; Netaneli ati Radai; Osemu ati Dafidi. Àwọn arabinrin wọn ni Seruaya ati Abigaili. Seruaya yìí ló bí Abiṣai, Joabu ati Asaheli. Abigaili fẹ́ Jeteri láti inú ìran Iṣimaeli, ó sì bí Amasa fún un.