I. Kro 2:1-17
I. Kro 2:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
WỌNYI ni awọn ọmọ Israeli; Rubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni, Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri. Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a. Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun. Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli. Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun. Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀. Awọn ọmọ Etani; Asariah. Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai. Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda; Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi. Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu àtẹle, ati Ṣimma ẹkẹta. Netanneeli ẹkẹrin, Raddai ẹkarun, Osemu ẹkẹfa, Dafidi ekeje: Awọn arabinrin wọn ni Seruiah ati Abigaili. Ati awọn ọmọ Seruiah; Abiṣai, ati Joabu, ati Asaeli, mẹta. Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli.
I. Kro 2:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni; Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri. Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á. Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera. Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli. Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada. Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Etani ni ó bí Asaraya. Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda, Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi, Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese. Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea; Netaneli ati Radai; Osemu ati Dafidi. Àwọn arabinrin wọn ni Seruaya ati Abigaili. Seruaya yìí ló bí Abiṣai, Joabu ati Asaheli. Abigaili fẹ́ Jeteri láti inú ìran Iṣimaeli, ó sì bí Amasa fún un.
I. Kro 2:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri. Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú OLúWA; Bẹ́ẹ̀ ni OLúWA sì pa á. Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀. Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu. Àwọn ọmọ Sera: Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún. Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀. Àwọn ọmọ Etani: Asariah. Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu. Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda. Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi, Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese. Jese sì ni baba Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu, ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea, Ẹlẹ́kẹrin Netaneli, ẹlẹ́karùnún Raddai, ẹlẹ́kẹfà Osemu àti ẹlẹ́keje Dafidi. Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili. Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli. Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli.