KRONIKA KINNI 17

17
Iṣẹ́ tí Natani Jẹ́ fún Dafidi
(2Sam 7:1-17)
1Ní ọjọ́ kan ní àkókò tí Dafidi ọba ń gbe ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani, wolii, pé, “Wò ó, èmi ń gbé ilé tí a fi igi kedari kọ́, ṣugbọn Àpótí Majẹmu OLUWA wà ninu àgọ́.”
2Natani bá dá a lóhùn pé, “Ṣe gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ, nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu rẹ.”
3Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an, Ọlọrun sọ fún Natani pé, 4“Lọ sọ fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, èmi ‘OLUWA sọ pé kì í ṣe òun ni óo kọ́ ilé tí n óo máa gbé fún mi. 5Nítorí pé n kò tíì gbé inú ilé kankan láti ìgbà tí mo ti kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò lóko ẹrú títí di òní. Inú àgọ́ kan ni mo ti ń dé inú àgọ́ mìíràn, tí mo sì ń lọ láti ibìkan dé ibòmíràn. 6Sọ pé, mo ní ninu gbogbo ibi tí mo ti ń bá àwọn ọmọ Israẹli lọ káàkiri, ǹjẹ́ mo tíì yanu bèèrè lọ́wọ́ onídàájọ́ kankan, lára àwọn tí mo pàṣẹ fún láti máa darí àwọn eniyan mi, pé kí wọ́n kọ́ ilé kedari fún mi?’
7“Nítorí náà, sọ fún un pé, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ‘mo mú un wá láti inú pápá, níbi tí ó ti ń da ẹran, pé kí ó wá jọba lórí, àwọn eniyan mi, Israẹli. 8Mo sì ń wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó ń lọ, mo sì ti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run níwájú rẹ̀, n óo sì gbé orúkọ rẹ̀ ga bí orúkọ àwọn eniyan ńlá ayé. 9N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo fìdí wọn múlẹ̀, wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́, àwọn ìkà kò tún ní ṣe wọ́n lófò mọ́ bíi ti àtijọ́, 10nígbà tí mo ti yan àwọn adájọ́ láti darí Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo tẹ orí àwọn ọ̀tá wọn ba. Bákan náà, èmi OLUWA ṣe ìlérí pe n óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀. 11Nígbà tí ọjọ́ bá pé tí ó bá kú, tí a sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀, n óo gbé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, àní ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin rẹ̀, n óo sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. 12Yóo kọ́ ilé kan fún mi, n óo jẹ́ kí atọmọdọmọ rẹ̀ wà lórí ìtẹ́ títí lae. 13N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi. N kò ní yẹ ìfẹ́ ńlá mi tí mo ní sí i, bí mo ti yẹ ti Saulu, tí ó ṣáájú rẹ̀. 14N óo fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ ní ilé mi ati ninu ìjọba mi títí lae. N óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.’ ”#2 Kọr 6:18; Heb 1:5
15Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni Natani sọ fún Dafidi, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí i lójú ìran.
Adura Ọpẹ́ tí Dafidi Gbà
(2Sam 7:18-29)
16Dafidi bá lọ jókòó níwájú OLUWA, ó gbadura báyìí pé, “Kí ni èmi ati ilé mi jẹ́, tí o fi gbé mi dé ipò tí mo dé yìí? 17Gbogbo èyí kò sì tó nǹkan lójú rẹ, Ọlọrun, o tún ṣèlérí nípa ìdílé èmi iranṣẹ rẹ fún ọjọ́ iwájú, o sì ti fi bí àwọn ìran tí ń bọ̀ yóo ti rí hàn mí, OLUWA Ọlọrun! 18Kí ni mo tún lè sọ nípa iyì tí o bù fún èmi, iranṣẹ rẹ? Nítorí pé o mọ èmi iranṣẹ rẹ. 19OLUWA, nítorí ti èmi iranṣẹ rẹ, ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni o fi ṣe àwọn nǹkan ńlá wọnyi, tí o sì fi wọ́n hàn. 20Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, OLUWA, kò sì sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti fi etí wa gbọ́. 21Ní gbogbo ayé, orílẹ̀-èdè wo ni ó tún dàbí Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí ìwọ Ọlọrun rà pada láti jẹ́ eniyan rẹ, tí o sì sọ orúkọ rẹ̀ di ńlá nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí o ṣe nígbà tí ó lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn eniyan rẹ, tí o rà pada láti ilẹ̀ Ijipti? 22O ti sọ àwọn eniyan rẹ, Israẹli, di tìrẹ títí lae, ìwọ OLUWA sì di Ọlọrun wọn.
23“Nisinsinyii, OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí o sọ nípa èmi iranṣẹ rẹ ṣẹ, ati ti ìran mi lẹ́yìn ọ̀la, kí o sì ṣe bí o ti wí. 24Orúkọ rẹ yóo fìdí múlẹ̀ sí i, àwọn eniyan rẹ yóo sì máa gbé ọ́ ga títí lae, wọn yóo máa wí pé ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ó jẹ́ Ọlọrun Israẹli ni Israẹli mọ̀ ní Ọlọrun,’ ati pé ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ, yóo fìdí múlẹ̀ sí i níwájú rẹ. 25Nítorí pé ìwọ Ọlọrun mi, ti fi han èmi iranṣẹ rẹ pé o óo fìdí ìdílé mi múlẹ̀, nítorí náà ni mo ṣe ní ìgboyà láti gbadura sí ọ. 26OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun, o ti ṣe ìlérí ohun rere yìí fún èmi iranṣẹ rẹ. 27Nítorí náà, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bukun ìdílé èmi iranṣẹ rẹ, kí ìdílé mi lè wà níwájú rẹ títí lae, nítorí ẹnikẹ́ni tí o bá bukun, olúwarẹ̀ di ẹni ibukun títí lae.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 17: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀