KRONIKA KINNI 16

16
1Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun kalẹ̀ ninu àgọ́ tí Dafidi ti tọ́jú sílẹ̀ fún un, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú Ọlọrun. 2Nígbà tí Dafidi rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA, 3ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, atọkunrin atobinrin, ní burẹdi kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran yíyan kọ̀ọ̀kan ati àkàrà èso resini.
4Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli. 5Asafu ni olórí, àwọn tí ipò wọn tún tẹ̀lé tirẹ̀ ni: Sakaraya, Jeieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Matitaya, Eliabu, Bẹnaya, Obedi Edomu ati Jeieli àwọn tí wọ́n ń ta hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù. Asafu ni ó ń lu aro. 6Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun. 7Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA.
Orin Ìyìn
(O. Daf 105:1-15; 96:1-13; 106:1, 47-48)
8Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA, ẹ képe orúkọ rẹ̀,
ẹ kéde ohun tí ó ti ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè.
9Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ sọ nípa àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe!
10Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo,
kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀.
11OLUWA ni kí ẹ máa tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́,
Ẹ máa sìn ín nígbà gbogbo.
12Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,
gbogbo nǹkan ìyanu tí ó ṣe, ati gbogbo ìdájọ́ rẹ̀,
13ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
14Òun ni OLUWA Ọlọrun wa,
ìdájọ́ rẹ̀ ká gbogbo ayé.
15Kò ní í gbàgbé majẹmu rẹ̀ títí lae,
àní àwọn ohun tí ó ti pa láṣẹ láti ṣe fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,
16majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,
ìlérí tí ó ti ṣe fún Isaaki,
17tí ó sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu Jakọbu,
gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ohun tí yóo wà títí lae,
18ó ní, “Ẹ̀yin ni n óo fún ní ilẹ̀ Kenaani,
bí ohun ìní yín, tí ẹ óo jogún.”#a Jẹn 12:7 b Jẹn 26:3 #Jẹn 28:13
19Nígbà tí wọn kò tíì pọ̀ pupọ,
tí wọn kò sì jẹ́ nǹkan,
tí wọ́n jẹ́ àjèjì níbẹ̀,
20tí wọn ń lọ káàkiri láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji,
láti ìjọba kan sí òmíràn,
21kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,
ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.
22Ó ní, “Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,
ẹ má sì pa àwọn wolii mi lára!”#Jẹn 20:3-7
23Ẹ kọrin sí OLUWA, gbogbo ayé!
Ẹ máa kéde ìgbàlà rẹ̀ lojoojumọ.
24Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,
ẹ polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan!
25OLUWA tóbi, ìyìn tọ́ sí i lọpọlọpọ
ó sì yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún un ju gbogbo àwọn oriṣa lọ.
26Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun,
ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run.
27Ògo ati agbára yí i ká,
ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀.
28Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé,
ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́!
29Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un,
ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀!
Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́,
30ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé,
ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae.
31Kí inú ọ̀run kí ó dùn,
kí ayé kí ó yọ̀,
kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!”
32Kí òkun ati ohun gbogbo tó wà ninu rẹ̀ hó yèè,
kí pápá oko búsáyọ̀, ati gbogbo ẹ̀dá tó wà ninu rẹ̀.
33Àwọn igi igbó yóo kọrin ayọ̀
níwájú OLUWA, nítorí ó wá láti ṣe ìdájọ́ ayé.
34Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA nítorí pé ó ṣeun,
ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ sì wà títí lae!#2Kron 5:13; 7:3; Ẹsr 3:11; O. Daf 100:5; 106:1; 107:1; 118:1; 136:1; Jer 33:11
35Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa,
kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,
kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ,
kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.
36Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,
lae ati laelae!”
Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA.
Ìjọ́sìn ní Gibeoni ati ní Jerusalẹmu
37Dafidi fi Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí iwájú Àpótí Majẹmu OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ lojoojumọ, 38pẹlu Obedi Edomu ati àwọn arakunrin rẹ̀ mejidinlaadọrin; ó sì fi Obedi Edomu, ọmọ Jedutuni ati Hosa ṣe aṣọ́nà.
39Ó fi Sadoku, alufaa ati àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ibi Àgọ́ OLUWA ní ibi pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Gibeoni, 40láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́, bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli. 41Hemani wà pẹlu wọn, ati Jedutuni ati àwọn mìíràn tí a yàn, tí a sì dárúkọ, láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí kì í yẹ̀. 42Hemani ati Jedutuni ní fèrè, aro, ati àwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn tí wọ́n fi ń kọrin ìyìn. Àwọn ọmọ Jedutuni ni wọ́n yàn láti máa ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà.
43Lẹ́yìn náà olukuluku pada sí ilé rẹ̀, Dafidi náà pada sí ilé rẹ̀ láti lọ súre fún àwọn ará ilé rẹ̀.#2Sam 6:19-20

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀