1
Isaiah 59:2
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isaiah 59:2
2
Isaiah 59:1
Lódodo ọwọ́ OLúWA kò kúrú láti gbàlà, tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.
Ṣàwárí Isaiah 59:1
3
Isaiah 59:21
“Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni OLúWA wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni OLúWA wí.
Ṣàwárí Isaiah 59:21
4
Isaiah 59:19
Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ OLúWA, àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀. Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi èyí tí èémí OLúWA ń tì lọ.
Ṣàwárí Isaiah 59:19
5
Isaiah 59:20
“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni, sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni OLúWA wí.
Ṣàwárí Isaiah 59:20
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò