“Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,
àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi,
bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùn
àti ọjọ́ mímọ́ OLúWA ní ohun ọ̀wọ̀
àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ
àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí
kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,
nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú OLúWA rẹ,
èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé,
àti láti máa jàdídùn ìní ti
Jakọbu baba rẹ.”
Ẹnu OLúWA ni ó ti sọ̀rọ̀.