Isa 58:4-5
Isa 58:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, ẹnyin ngbãwẹ̀ fun ìja ati ãwọ̀, ati lilù, nipa ikũku ìwa-buburu: ẹ máṣe gbãwẹ bi ti ọjọ yi, ki a le gbọ́ ohùn nyin li oke. Ãwẹ̀ iru eyi ni mo yàn bi? ọjọ ti enia njẹ ọkàn rẹ̀ ni ìya? lati tẹ ori rẹ̀ ba bi koriko odo? ati lati tẹ́ aṣọ ọ̀fọ ati ẽru labẹ rẹ̀? iwọ o ha pe eyi ni ãwẹ̀, ati ọjọ itẹwọgba fun Oluwa?
Isa 58:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín, ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà. Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run. Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán? Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni? Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan? Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA?
Isa 58:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀, àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu. Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga. Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí, ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀? Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú? Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí, ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLúWA?