1
Jak 3:17
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn ọgbọ́n ti o ti oke wá, a kọ́ mọ́, a si ni alafia, a ni ipamọra, kì isí iṣoro lati bẹ̀, a kún fun ãnu ati fun eso rere, li aisi ègbè, ati laisi agabagebe.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Jak 3:17
2
Jak 3:13
Tali o gbọ́n ti o si ni imọ̀ ninu nyin? ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa ìwa rere, nipa ìwa tutù ti ọgbọn.
Ṣàwárí Jak 3:13
3
Jak 3:18
Eso ododo li a ngbìn li alafia fun awọn ti nṣiṣẹ alafia.
Ṣàwárí Jak 3:18
4
Jak 3:16
Nitori ibiti owú on ìja bá gbé wà, nibẹ̀ ni rudurudu ati iṣẹ buburu gbogbo wà.
Ṣàwárí Jak 3:16
5
Jak 3:9-10
On li awa fi nyìn Oluwa ati Baba, on li a si fi mbú enia, ti a dá li aworan Ọlọrun. Lati ẹnu kanna ni iyìn ati ẽbú ti njade. Ẹnyin ará mi, nkan wọnyi kò yẹ ki o ri bẹ̃.
Ṣàwárí Jak 3:9-10
6
Jak 3:6
Iná si ni ahọ́n, aiye ẹ̀ṣẹ si ni: li arin awọn ẹ̀ya ara wa, li ahọn ti mba gbogbo ara jẹ́ ti o si ntinabọ ipa aiye wa; ọrun apãdi si ntinabọ on na.
Ṣàwárí Jak 3:6
7
Jak 3:8
Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni.
Ṣàwárí Jak 3:8
8
Jak 3:1
ẸNYIN ará mi, ẹ máṣe jẹ olukọni pipọ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awa ni yio jẹbi ju.
Ṣàwárí Jak 3:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò