Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joṣ 1:8

Ọ̀nà Ọlọ́run sí Àṣeyọrí
Ojo meta
Gbogbo ènìyàn ló ńwá àṣeyọrí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni kò rí i nítorípé ohun tí wọn ń lé ní òye àdàmọ̀dì lórí ohun tí gbígbé ìgbé ayé àṣeyọrí túmọ̀ sí. Kí a tó lè rí àṣeyọrí tòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbá'jú mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó túmọ̀ sí. Jẹ́ kí gbajúgbajà òǹkọ̀wé nì Tony Evans fí ọ̀nà sí àṣeyọrí tóòtọ́ ti ìjọba Ọlọ́run hàn ọ́ àti bí ọ ṣe lè wá a rí.

Wíwá Àyè Fún Ìsinmi
Ọjọ́ márùn-ún
Isé àsekúdórógbó àti isé lemólemó jé ohun tí a sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fún ní Ayé wa, àtipé ó lè jẹ́ ìpèníjà láti simi. Kí a bá lè se ojuse wa àti àwon ètò lónà tó já fáfá, a gbódò kọ́ láti sinmi tàbí a kò ni ní ohunkóhun tó máa sékù láti ṣètìlẹyìn fún àwon tí a féràn àti sí àwon ìlépa tí a gbé kalẹ̀. Ẹ jé kí a lo ọjọ́ márùn-ún tó tè lé fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsimi àti bí a se lè fi ohun tí a kọ́ sí inú ayé wa.

Irin Ń Lọ Irin: Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí® Ìtọ́ni nínú Májẹ̀mú Láéláé
Ojọ́ Márùn-ún
Ǹjẹ́ òun wòye láti “sọ di ọmọ ẹ̀yìn tó n sọ di omo ẹ̀yìn,” láti tẹ̀lé ìlànà Jésù nínú Àṣẹ Ńlá (Mátíù 28:18-20)? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o leè ti ríi pé ó lè nira láti rí ẹni tí a kò bá fi ṣe olùtọ́ni sọ́nà fún ìgbésẹ̀ yí. Àpẹẹrẹ ta ni o leè tẹ̀lé? Báwo ni sí sọ ni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́? Ẹ jẹ́ kí a wo inú Májẹ̀mú Àtijó láti wo bí àwọn ọkùnrin márùn àti obìnrin ṣe bu omi rin ayé àwọn míràn, Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ®.

Wiwo Bibeli ti Aisiki
5 Awọn ọjọ
Lẹ́yìn ikú Mósè, Ọlọ́run fún Jóṣúà ní àwòkọ́ṣe kan fún jíjẹ́ aásìkí àti àṣeyọrí rere. Nínú ìfọkànsìn ti ọ̀sẹ̀ yìí, a óò gbé àdàkọ yìí yẹ̀wò fínnífínní, ní ṣíṣàyẹ̀wò bí ó ṣe tan mọ́ onígbàgbọ́ òde òní, kí a sì gbára lé Ọlọ́run fún ìjìnlẹ̀ òye sí àwọn òtítọ́ tí ó wà nínú ìmọ̀ràn náà.

Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtì
Ọjọ́ Méje
Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.

Ìgboyà
Ọ̀sẹ̀ kan
Kọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgboyà. Ètò kíkà “Ìgboyà” rán àwọn onígbàgbọ́ létí ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú Kristi àti nínú ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí a bá jẹ́ ti Ọlọrun, a ní òmìnira láti súnmọ́-On tààrà. Kà lẹ́ẹ̀kansi - tàbí bóyá fún ìgbà àkọ́kọ́ - àwọn ìdánilójú pé ipò rẹ nínú ìdílé Ọlọrun wà síbẹ̀.